Ẹ wo Daud, Eko lo ti lọọ jale n’Ijẹbu-Ode

Aderounmu Kazeem

Ọkunrin yii, Daud James, ti n mura lati lọọ rojọ niwaju adajọ bayii pẹlu oriṣiiriṣii ẹsun ole ti wọn fi kan an laipẹ yii.

Lọjọ kọkanlelogun, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, lọwọ ọlọpaa tẹ ẹ nibi to ti dọgbọn paarọ kaadi, ATM tawọn eeyan fi maa n gbowo ni banki.

Wọn ni deede aago mẹsan-an aarọ ni ọga ọlọpaa agbegbe Igbeba, niluu Ijẹbu-Ode, nipinlẹ Ogun, gba ipe pe ọkunrin janduku kan ti lo ọgbọn alumọkọrọyi fi ji kaadi ATM lọwọ awọn eeyan ni banki kan lagbegbe naa.

Wọn lo pẹ ti Daud James ti n ṣiṣẹ ibi yii, ati pe laaarọ ọjọ yẹn gan-an, niṣe lo fọgbọn paarọ kaadi ATM mọ awọn eeyan meji kan lọwọ, to si ko gbogbo owo to wa ninu apo ikowopamọsi wọn lọ.

Owo ti wọn lo ba ninu apo ikowopamọsi awọn eeyan meji tọwọ ẹ tẹ kaadi wọn yii jẹ ẹgbẹrun lọna ogoji naira (#40,000) ati ẹgbẹrun lọna marundinlọgota naira (#55,000).

Wọn ni lasiko ti ọkan ninu awọn to ti ja lole tẹlẹ tun ri i ni banki mi-in, nibi to tun ti fẹẹ fọgbọn paarọ kaadi mọ ẹlomi-in lọwọ niyẹn fariwo ta, ti ọrọ si di ti ọlọpaa.

Ọkunrin ti wọn fẹsun kan yii naa ba akọroyin wa sọrọ, alaye to ṣe ni pe ilu Eko loun n gbe, ati pe nigba ti baba oun ku lojiji, ti oun ko ri nnkan kan ṣe mọ, loun bẹrẹ iṣẹ ̀ọhun.

O ni gbogbo owo ti oun ri lẹnu iṣẹ buruku ọhun ko ju ẹgbẹrun lọna marundinlọgọrun-un naira lọ.

Bakan naa ni Daud sọ pe Ijẹbu-Ode lọwọ ti tẹ oun lasiko ti oun lọọ ki eeyan kan nibẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ẹni ọdun mọkandinlogoji lo pe ara ẹ, o loun ko ti i niyawo, bẹẹ lẹnikẹni ko kọ oun niṣẹ naa, ati pe oun nikan loun n da a ṣe, oun ko ni ọmọọṣẹ kankan tabi ọga ti oun n ja’bọ fun.

Yatọ si bo ṣẹ maa n paarọ kaadi ATM mọ awọn eeyan lọwọ yii, ọna mi-in to tun loun maa n gba ni ti oun ba ri kaadi ATM nilẹ, niṣe loun yoo mu un, ti owo ba si wa ninu apo ikowosi iru ẹni bẹẹ, gbogbo ẹ pata loun yoo ko ni toun.

Ọkunrin ọmọ Auchi, nipinlẹ Edo, yii ti sọ pe ohun itiju nla ni iṣẹlẹ ọhun jẹ foun, ati pe oun ti kẹkọọ bayii, ti oun ba si fi le bọ, a jẹ pe ipinya nla de ba oun ati Eṣu pẹlu awọn iṣẹ ibi ẹ niyẹn.

Ṣa o, ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe iwaju adajọ ni  yoo ti mọ ohun ti yoo jẹ ipin ẹ lori ẹsun ti wọn fi kan an yii.

Leave a Reply