Ẹ wo Ibrahim: Igbakeji ọga awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun, ibọn rẹpẹtẹ ni wọn ba lọwọ ẹ

Adewale Adeoye

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fọwọ ofin mu Ọgbẹni Ibrahim AbdulAzeez, ti wọn sọ pe ogbologboo ọmọ ẹgbẹ okunkun ni, ati pe ọpọ igba lo maa n fipa ba awọn ọmọbinrin sun lagbegbe Imaweje, niluu Ijẹbu-Igbo, ipinlẹ Ogun.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago meji aabọ ọsan ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii, lọwọ awọn ọlọpaa to ti n dọdẹ rẹ to o, ti wọn si fọwọ ofin gba a mu. Oniruuru ohun ija oloro ni wọn ba lọwọ rẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, S.P Ọmọlọla Odutọla, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lori foonu lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, sọ pe yatọ si pe Ibrahim jẹ ọdaran tawọn agbofinro n wa, oun yii kan naa ni igbakeji olori ẹgbẹ okunkun kan to maa n da alaafia agbegbe ibi to n gbe laamu gidi, to si maa n ba awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Aye tọju ibọn ti wọn n lo pamọ.

Odutọla ni, ‘’Igbakeji olori ẹgbẹ okunkun Aye ni Ibrahim yii, idi ree ti wọn ṣe n pe e ni ‘Alapata’ laarin wọn. Ẹmi eeyan ko jọ ọ loju rara, oun yii kan naa lo da bii igi lẹyin ọgba awọn yooku rẹ, ọdọ rẹ ni awọn ojulowo irinṣẹ ti wọn n lo wa, awọn irinṣẹ yii lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun maa n lo lati fi ṣiṣẹ buruku ọwọ wọn niluu Ijẹbu-Ode nigba gbogbo. Ikọ akanṣe ọlọpaa kan to ti n dọdẹ rẹ lo lọọ fọwọ ofin mu un nile rẹ.

‘‘Lẹyin ta a gba mu tan lo jẹwọ pe ọmọ ileewe ‘Tai Ṣolarin University Of Technology’, to wa lagbegbe Ijegun, loun, gbogbo iṣẹ ibi pata lo kun ọwọ rẹ, o n fipa ba awọn ọmọbinrin sun, o n ṣiṣẹ ijinigbe, o tun n ba awọn ọmọ ẹgbe okunkun tọju ibọn ti wọn n lo pamọ.

Lara awọn nnkan ija oloro ta a ba nile rẹ lasiko ti wọn si mu un ni, ibọn oloju meji to jẹ ti oyinbo kan, ọpọlọpọ ọta ibọn, ibọn ṣakabula ti ibilẹ ati awọn oniruuru ohun ija oloro mi-in lo wa lọwọ rẹ.

Nigbẹyin, Alukoro ni awọn maa too foju rẹ bale-ẹjọ laipẹ yii.

Leave a Reply