O ma waa ga o, agbebọn mura bii ẹlẹhaa, lo ba pa ọga ọlọpaa meji danu

Adewale Adeoye

Ṣe lọrọ ọhun di ẹni ori yọ, ipade dile, lasiko ti agbebọn kan to mura bii ẹlẹhaa lọọ kọju ibọn sawọn ọlọpaa kan to n ṣiṣẹ lojuna marosẹ ọna Jibia si Baltsari, nipinlẹ Katsina, to si pa ọga ọlọpaa meji kan danu loju-ẹsẹ lọjọ naa. Inu igbo nla kan to wa lagbegbe Gurbin-Magarya, nibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye lawọn ọlọpaa yooku mori le, ibẹ ni wọn gba sa lọ patapata.

ALAROYE gbọ pe lẹyin tawọn agbofinro ọhun sa lọ ni ọdaran ọhun tun lọọ palẹmọ gbogbo ibọn awọn agbofinro ti wọn gbagbe silẹ lasiko ti wọn n sa asala fun ẹmi wọn, toun naa si sa lọ patapata.

Ọga ọlọpaa kan to gba lati sọrọ nipa iṣẹlẹ kayeefi ọhun, ṣugbọn ti ko darukọ ara rẹ sọ pe Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii, ni iṣẹlẹ laabi ọhun waye.

O ni ikọ ọlọpaa kan ti wọn maa n lọ kaakiri aarin ilu lati pese aabo fawọn araalu ni awọn Insipẹkitọ meji to padanu ẹmi wọn yii wa, ti wọn si ti gbe oku wọn lọ si mọṣuari kan to wa niluu Katsina.

Ọrọ awọn agbebọn naa ti waa di egbinrin ọtẹ bayii, bi wọn ṣe n pa ọkan ni omi-in n ru. O fẹrẹ ma si agbegbe ti wọn ki i ti i ṣọṣẹ mọ bayii kaakiri orileede yii.

Leave a Reply