Orileede Mali, Niger ati Burkina-Faso ti kuro ninu ajọ ECOWAS

Adewale Adeoye

Ni bayii, awọn ijọba ologun ti orileede Mali, Niger ati Burkina-Faso, ti kede pe awọn ti kuro ninu ajọ ‘Economic Community Of West Africa State’ (ECOWAS), nitori bawọn alaṣẹ ajọ ọhun ṣe fofin de orileede awọn latigba ti ọrọ iditẹ-gbajọba ti waye lawọn orileede ọhun.

Ọgagun Amadou Abdramane, ti i ṣe agbẹnusọ ijọba ologun orileede Niger lo gba ẹnu awọn olori orileede yooku sọrọ lori ẹrọ tẹlifiṣan ijọba orileede Niger, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii.

Ọgagun Amadou ni, ‘Lẹyin ta a foju ṣunnukun wo ọrọ ajọ ECOWAS yii daadaa, o jẹ ohun ẹdun ọkan ati ohun ibanujẹ nla pe lẹyin ọdun mọkandinlaaadọta tawọn baba nla wa ti da ajọ ọhun silẹ, awọn to n ṣakoso rẹ lọwọ yii ti kuna lati tẹle ilana ati ofin tawọn to da a silẹ fi lelẹ patapata. Idi ree ta a ṣe kuro ninu ajọ ọhun bayii, nitori ki i ṣe ajọ to le mu ilọsiwaju gidi ba orileede wa rara. Wọn ko dide iranlọwọ kankan si wa lasiko ta a n koju oke iṣoro lọwọ awọn afẹmiṣofo. Bẹẹ ni ko si iranlọwọ kankan fun wa lasiko laaṣigbo wa’’.

Latigba ti iditẹ-gbajọba ti waye lawọn orileede ọhun ni nnkan ko ti fara rọ mọ laarin awọn ologun to ditẹ-gbajọba lọwọ awọn alagbada orileede ọhun atawọn alaṣẹ ajọ ECOWAS yii.

Inu oṣu Keje, ọdun 2023, ni iditẹ-gbajọba waye lorileede Niger, ọdun 2022 ni iditẹ-gbajọba waye lorileede Burkina-Faso, nigba ti iditẹ-gbajọba waye lorileede Mali lọdun 2022.

Latigba tawọn ologun orileede ọhun ti ditẹ-gbajọba lọwọ ijọba alagbada orileede wọn ni ajọ ECOWAS ti fofin de wọn, koda, wọn fẹẹ lọọ kogun ja wọn ki wọn si le awọn ijọba ologun naa kuro lori oye lasiko naa. Ṣugbọn nigba to maa fi di oṣu Kẹsan-an, ọdun to kọja yii, ni awọn ijọba ologun orileede mẹta ọhun ba tọwọ-bọwe adehun laarin ara wọn lati gbeja ara wọn, iyẹn bi ajọ ECOWAS ba gbiyanju lati waa kogun ja wọn.

Ṣa o, awọn alaṣẹ ajọ ECOWAS ti ni ko soootọ kankan ninu ọrọ ọhun pe awọn alaṣẹ orileede mẹta ọhun ti kuro ninu ajọ naa bayii. Wọn ni wọn ko ti i kọwe fi ranṣẹ sawọn gẹgẹ bii ilana ti ofin sọ.

 

Leave a Reply