O ma ṣe o, iyawo atawọn ọrẹ ẹ marun-un pẹlu aburo ọkọ ku sinu ijamba mọto lọjọ kan naa

Adewale Adeoye

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii ni iṣẹlẹ agbọ-kawọ-mọri kan ṣẹlẹ sawọn  idile kan to ṣẹṣẹ ṣegbeyawo alarinrin fawọn ọmọ wọn, ti iyawo ọhun atawọn kan si ku sinu ijamba ọkọ to waye laipẹ yii. Iyawo to ṣẹṣẹ ṣegbeyawo, aburo ọkọ rẹ ọkunrin atawọn ọrẹ iyawo bii marun-un ni wọn nijamba ọkọ lasiko ti wọn n pada lọ silẹ wọn, ti gbogbo wọn si ku loju-ẹsẹ.

Iṣẹlẹ kayeefi ọhun waye lojuna marosẹ kan to wa lagbegbe Lukoro, niluu kekere kan ti wọn n pe ni Edati, nipinlẹ Niger lọhun-un.

ALAROYE gbọ pe mẹwaa ninu awọn to padanu ẹmi wọn yii lo jẹ akẹkọọ gboye nileewe giga kan ti wọn n pe ni ‘Sultan Abdulraman College Of Health Technology’, to wa ni Gwadabawa.

Awọn akẹkọọ ọhun ni wọn kora wọn jọ lati lọọ ba ọkan lara ọrẹ wọn, Oloogbe Amina toun naa jẹ akẹkọọ nileewe ọhun lọọ ṣẹyẹ igbeyawo to waye laarin ọmọbinrin yii ati ololufẹ rẹ, Ọgbẹni Umar jibril Muhammad, toun naa jẹ akẹkọọ nileewe naa.

Nibi ti wọn ti n pada lọ sile ni ọkọ wọn ti lọọ fori sọ mọto mi-in, ti ọpọ ẹmi si ba iṣẹlẹ ọhun lọ loju-ẹsẹ.

Ere asapajude ti ọkan lara awọn mọto meji to fori sọ ara wọn ọhun n sa lọjọ naa lo ṣokunfa ijamba buruku ọhun. Mọto ayọkẹlẹ ‘Toyota Corolla’, alawọ eeru kan tawọn to ṣẹṣẹ ṣegbeyawo yii wa ninu rẹ n bọ lati ilu Mokwa, o si n pada lọ siluu Bida, nigba ti mọto akero Nissan kan ti wọn jọ lasidẹẹti n bọ lati ilu Minna, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Niger, to si n lọ siluu Ogbomọṣọ, nipinlẹ Ọyọ.

Ọga agba ajọ to n ri si igbokegbodo ọkọ loju popo, ‘Federal Road Safety Corps’ (FRSC) ẹka tiluu naa, Ọgbẹni Tsukwan Kumar, ni awọn obinrin agbalagba mẹjọ, ọkunrin mẹrin ati ọmọde kan, ni wọn ku loju-ẹsẹ ninu ijamba ọhun.

O fi kun ọrọ rẹ pe awọn obinrin mẹrin, ọkunrin kan ati ọmọdebinrin kan ti wọn fara pa gidi ninu ijamba mọto ọhun lawọn ti gbe lọ sileewosan ijọba, ‘Federal Medical Center (FMC) to wa lagbegbe ibi ti iṣẹle ọhun ti waye, tawọn dokita si ti n ṣetọju wọn lọwọ bayii.

O ni oku awọn mẹsan-an kan ni wọn ti gbe fawọn eeyan wọn niwọn igba to jẹ pe awọn ẹbi wọn le tọka si oku eeyan wọn. Nigba ti wọn ko oku awọn mẹrin yooku lọ si mọsuari kan to wa nileewosan ijọba agbegbe kan ti wọn n pe ni Kutigi.

 

Leave a Reply