Iru ifẹ wo ree: Nitori ti ọkunrin ja a kulẹ, akẹkọọ-binrin yii binu gbẹmi ara ẹ

Monisọla Saka

Akẹkọọ-binrin onipele keji nileewe gbogboniṣe ijọba apapọ to wa niluu Mubi, nipinlẹ Adamawa (Federal Polytechnic, Mubi), Jamima Shetima Balami, ti ran ara ẹ sọrun ọsan gangan. Eyi ko sẹyin bi ọrẹkunrin rẹ ṣe fopin si irinajo ifẹ to wa laarin wọn.

Obinrin ẹni ọdun mẹrinlelogun (24), to n ṣe ọkan lara eto ti ileewe naa la kalẹ fun gbogbo akẹkọọ to wa nipele keji lati maa ṣe ni awọn ileeṣẹ kaakiri lati fi imọ kun imọ, eyi ti wọn n pe ni IT lọwọ nileeṣẹ tẹlifiṣan ipinlẹ Adamawa (Adamawa Television ATV), ni wọn lo pa ara ẹ lẹyin to gbe majele jẹ ninu ile ẹ to wa lagbegbe Vinikilang, nijọba ibilẹ Girei, nipinlẹ naa.

ALAROYE gbọ pe olukọ ni ọrẹkunrin Jamima yii nileewe giga Fasiti Modibbo Adama (MAU), ṣugbọn ti wọn ko darukọ ẹ. Lojiji lo deede yọ ṣọọki lẹsẹ ọmọbinrin to ti ni igbẹkẹle ninu rẹ pe oun loun maa fi ṣe ade ori, ti ọmọkunrin naa yoo si gbe oun sile bii iyawo yii, to si sọ fun un pe oun ko ṣe mọ. Ọrọ yii ni wọn lo wọn ọmọbinrin naa lara gidigidi nitori ifẹ to ni si afẹsọna rẹ yii ati igbẹkẹle rẹ pe oun ni yoo jẹ ọkọ oun. N ọmọbinrin ti wọn ni oun nikan ṣoṣo ni baba ẹ bi yii ba tori ohun ti ọrẹkunrin ẹ sọ fun un gbe majele jẹ, to si binu para ẹ.

Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Adamawa, SP Suleiman Yahaya Nguroje, to sọrọ ọhun fawọn oniroyin ṣalaye pe baba oloogbe lo waa fọrọ naa to awọn agbofinro leti. O ni iwadii ṣi n lọ lai duro lori ọrọ naa, nitori oriṣii ọna meji ni wọn gba gbe ọrọ ọhun kalẹ. Akọkọ ni pe oogun ekute ti ọmọbinrin naa gbe jẹ lọ sọ ọ dero ọrun, nigba ti omi-in tun fidi ẹ mulẹ pe funra Jamima lo gba ọrẹkunrin ẹ yii lalejo. Ati pe ibinu pe ọkunrin ọhun ni ki kaluku maa lọ lọtọọtọ lo mu ki akẹkọọ-binrin naa gbe nnkan jẹ.

Eyi o wu ko jẹ, Jamima ti para ẹ nitori pe ọrẹkunrin rẹ to ti nigbẹkẹle ninu loun ko fẹ ẹ mọ.

Leave a Reply