Ọpẹ o, wọn ti ri akẹkọọ Fasiti Ilọrin ti wọn ji gbe pada, eyi ni bi wọn ṣe ri i

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Akẹkọọ Fasiti ilu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, Moyọṣọrẹ Bright, to wa ni ipele kin-in-ni lẹka ẹkọ imọ ẹkọ nipa ẹranko, Zuọlọji, tawọn ajinigbe kan ji gbe ninu ọgba ileewe naa ti gbominira kuro lakata wọn bayii.

ALAROYE, gbọ pe ni nnkan bii aago meji ọsan ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ to kọja yii, ni Moyọṣọrẹ wọ bọọsi kekere (Korope) ninu ọgba ileewe naa, to si n lọ si agbegbe Táńkẹ̀, niluu Ilọrin, ṣugbọn to ko ṣọwọ awọn ajinigbe, ti wọn si pada ri i ninu igbo kan lẹyin ilu, tawọn ajinigbe naa si ti gba gbogbo dukia ti wọn ba lọwọ rẹ lọ.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ejirẹ Adeyẹmi Adetoun, fi lede lọjọ Aiku, Sannde, opin ọsẹ yii, lo ti fi idi ọrọ naa mulẹ pe akẹkọọ-binrin ọhun ti wa ọna lati bọ si igboro pada funra rẹ lẹyin to bọ lọwọ awọn ajinigbe to ji i gbe.

Adetoun ni ṣaaju lawọn kan ti mu ẹsun lọ si ileeṣẹ ọlọpaa lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu yii, pe wọn ji akẹkọọ naa gbe ninu ọgba ileewe, eyi lo mu ki awọn ọlọpaa agbegbe Táńkẹ́, bẹrẹ iwadii lẹṣẹkẹṣẹ.

O tẹsiwaju pe iwadii fidiẹ ẹ mulẹ pe lọjọ ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kin-in-ni yii, ni ọmọbinrin akẹkọọ naa, Moyọṣọrẹ Bright, wọ ọkọ korope ninu ọgba ileewe naa lasiko to n dari lọ sileegbe rẹ ni Táńkẹ̀, niluu Ilọrin. Sugbọn wọn ri i doola ninu igbo ti wọn gbe e lọ, ti wọn si ti gba gbogbo dukia rẹ bii ATM kaadi, ṣeeni goolu to wọ sọrun ati ẹgbẹrun mẹta Naira (3,000).

Adetoun ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lati mu awọn to wa nidii iwa buruku naa.

Kọmisana ọlọpaa ni Kwara, Victor Ọlaiya, ni ileeṣẹ ọlọpaa ko ni kaaarẹ ọkan lati maa daabo bo gbogbo olugbe ipinlẹ ọhun.

Leave a Reply