Ẹ woju awọn adigunjale to n yọ wọn lẹnu l’Ajegunlẹ Faith Adebọla, Eko

Faith Adebọla

Mẹfa ni wọn, gende si ni wọn, ọjọ-ori wọn ko ju aarin ọdun mejidinlogun si mẹẹẹdọgbọn pere lọ, amọ iṣẹ kan naa lo pa wọn pọ, iṣẹ adigunjale ni wọn n ṣe, iṣẹ naa si ti sọ wọn dero ahamọ ọlọpaa nigba tọwọ awọn agbofinro tẹ wọn nibuba wọn l’Ekoo.

Orukọ awọn afurasi ọdaran ọhun ni Emmanuel Chukwuemeka, ẹni ọdun mọkanlelogun, Innocent Chukwuebuka, ẹni ọdun mẹrinlelogun, Isah Umaru, ẹni ọdun mọkanlelogun, Emmanuel Itah, ẹni ọdun mọkandinlogun, Ọlaitan Ayinde, lọjọ ori ẹ kere ju laarin wọn, ọmọọdun mejidinlogun pere ni, nigba ti eyi to dagba ju, Moshood Ayinde, jẹ ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, to fiṣẹlẹ yii to Alaroye leti ninu atẹjade kan to fi sọwọ si wa lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹta yii, sọ pe mẹfa lawọn afurasi naa, ṣugbọn ikọ adigunjale meji ni wọn, mẹta mẹta ni wọn n jade lọjọ ti wọn ba fẹẹ lọọ ṣe araalu ni ṣuta.

O ni awọn firi-nidii-ọkẹ, alọ-kolohun-kigbe yii ti jẹwọ fawọn agbofinro pe agbegbe Ajegunlẹ ni ikọ akọkọ ti n jale, nigba ti igun keji yan agbegbe Alaba-Rago, laayo lati maa pa araalu lẹkun ni tiwọn.

O ni awọn araalu kan ti wọn ti n ṣọ wọn, ti wọn si mọ pe irin wọn ko mọ, ni wọn ta awọn lolobo, eyi lo mu kawọn ọtẹlẹmuyẹ fọn ka sawọn agbegbe naa, ti wọn si bẹrẹ si i ṣa wọn lọkọọkan. Hundeyin ni funra wọn ni wọn n juwe awọn ẹlẹgbẹ wọn yooku, ati ibi ti wọn fi ṣe ibuba, ti wọn ti ri wọn mu kaakiri.

Lara nnkan ti wọn ka mọ wọn lọwọ ni ọkada TVS kan ti ko si nọmba lara, ko si niwee, ibọn agbelẹrọ kan, foonu Infinix Note 7 kan, foonu Iphone 7 kan, oogun abẹnugọngọ ti wọn so mọra, ati egboogi oloro ti wọn fura pe igbo ni.

Hundeyin ni awọn ti fiṣẹlẹ yii to kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Idowu Owohunwa, leti, o si ti ni kawọn ọtẹlẹmuyẹ tubọ tẹ awọn afurasi yii ninu daadaa, ki wọn ṣewadii to lọọrin lori wọn.

Akata awọn ọtẹlẹmuyẹ naa ni wọn wa bayii ni Panti, Yaba, ibẹ ni wọn yoo gba dele-ẹjọ laipẹ, gẹgẹ bo ṣe wi.

Leave a Reply