Lẹyin to yege ibo aarẹ, Tinubu ṣabẹwo si Ọba Akiolu l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Bii igba tawọn jagunjagun aye ọjọun ba jagun ajaye, ti wọn si fẹẹ wọlu pada lọrọ ri lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ karun-un, oṣu Kẹta yii, pẹlu bi obitibiti ero ṣe tu jade lati ki aarẹ tuntun, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, kaabọ pada siluu Eko, lati Abuja.

Tilu-tifọn lawọn ololufẹ eekan oloṣelu to ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Eko naa lọọ pade rẹ, bi wọn ṣe n kọrin, bẹẹ ni wọn n jo, ti wọn si n kokiki rẹ gẹgẹ bii akọni ọkunrin to gbounjẹ fẹgbẹ, to si gbawo bọ.

Lati papakọ ofurufu Murtala Mohammed, MMIA, to wa n’Ikẹja, lawọn eekan eekan lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, ti lọọ pade Jagaban, gẹgẹ bi wọn ṣe n pe ọkan ninu awọn orukọ oye rẹ.

Lara awọn ti wọn lọọ ki i kaabọ ni Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, Olori awọn oṣiṣẹ ọba, Ọgbẹni Tayọ Ayinde, Sẹnetọ Musiliu Ọbanikoro, ati awọn oṣiṣẹ ọba mi-in.

Lati Ikẹja ọhun ni gbogbo wọn ti kọwọọrin pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ bọginni wọn gbogbo, taara ni wọn mori le aafin Iga-Iduganran, ibẹ ni Ọba Rilwanu Akiola, Ọba ilu Eko, ti ki Tinubu kaabọ, bẹẹ lẹsẹ awọn oloye onifila funfun niluu Eko pe ṣibaṣiba.

Ṣe tewe-tagba ni i ṣapẹ wo Liili, iṣẹ aṣelaagun lawọn ẹṣọ alaabo atawọn ọtẹlẹmuyẹ ṣe ki wọn too jẹ ki Tinubu bọọlẹ ninu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ, irin ti ko yẹ ko gba ju iṣẹju perete naa si gba akoko gigun ko too raaye wọle, bo ti n ṣiṣẹ lọkọọkan lo n juwọ sawọn ogunlọgọ ti wọn waa ṣayẹsi rẹ ọhun.

Laafin Ọba Akiolu, Tinubu ni irinajo toun la kọja lati asiko idibo abẹlẹ ti wọn fi fa oun kalẹ gẹgẹ bii oludije, titi digba ti eto idibo naa fi waye, to si pari lọsẹ to lọ yii, ko yatọ si idije ife agbaye bọọlu alafẹsẹgba to maa n waye, nibi to jẹ oju ogun ati ere ẹlẹmii ẹṣin ni, sibẹ ẹgbẹ kan ṣoṣo ni yoo gbe ife lọọ sile.

O dupẹ lọwọ Ọlọrun atawọn eeyan fun aṣeyọri rẹ, bakan naa lo dupẹ gidigidi lọwọ Ọba Akiolu atawọn ori-ade gbogbo fun adura ati ifẹ wọn.

Lẹyin eyi lo ṣafihan iwe-ẹri ‘mo yege’ ti ajọ eleto idibo INEC fun un, o si ya fọto pẹlu Ọba atawọn ijoye lati ṣeranti iṣẹlẹ amọkanyọ ọhun.

O waa ṣeleri pe gbogbo ẹjẹ toun jẹ lasiko idibo loun yoo ṣiṣẹ le lori, oun o si ni i ja awọn to rọjo ibo foun ati gbogbo ọmọ Naijiria kulẹ toun ba ti gbọpa aṣẹ laipẹ.

Leave a Reply