Ko saaye lati tun hu oku akẹkọọ Chrisland fun ayẹwo mi-in – Ijọba Eko

Faith Adebọla

Ijọba ipinlẹ Eko ti lawọn o ni in lọkan, awọn o si ni i faaye gba pe kẹnikẹni tun lọọ hu oku ọmọbinrin akẹkọọ ileewe Chrisland, Whitney Ọmọdeṣọla Adeniran, to ku lojiji loṣu to kọja, wọn lẹnikẹni to ba da iru ẹ laṣa yoo foju wina ofin ni.

Bakan naa nijọba lawọn ti gba esi ayẹwo ti wọn ṣe si oku akẹkọọ naa, awọn si ti n ṣewadii lori ẹ, ati pe ayẹwo naa fidi ẹ mulẹ pe niṣe lakẹkọọ yii gan mọna ẹlẹntiriiki to fi ku.

Kọmiṣanna feto ẹkọ nipinlẹ Eko lo sọrọ yii di mimọ lopin ọsẹ to kọja yii, lasiko to lọọ ṣabẹwo sawọn obi oloogbe ọhun, tọkọ-taya Adeniran ni ile wọn to wa ni Ẹsiteeti Ogudu, latari ọfọ to ṣẹ wọn ọhun.

Adefisayọ ni ko si ani-ani pe ibanujẹ nla to n sori agba kodo niṣẹlẹ ọhun, o ni bo ṣe ka awọn obi ati mọlẹbi ọmọdebinrin naa lara, bẹẹ nijọba Eko naa mọ ọn lara, tori ẹ si ni Gomina Babajide Sanwo-Olu ṣe gbe oun dide lati ṣabẹwo ibanikẹdun si wọn.

O waa fi da wọn loju pe ijọba ko ni i daṣọ bo iṣẹlẹ naa lori rara, o lawọn ti n ṣayẹwo si esi iwadii ijinlẹ lati mọ iru iku to pa ọmọ naa, ati pe gbogbo ika to ba ṣẹ lori ọrọ ohun, gige ni ida ofin ijọba yoo ge ika naa.

Bakan naa ni ẹka eto idajọ nipinlẹ Eko, Ministry of Justice, ti sọ pe awọn ti n gbọ finrin-finrin kan labẹnu, pe awọn alaṣẹ ileewe Chrisland kan fẹẹ gbe igbesẹ lati lọọ hu oku ọmọbinrin ọhun, wọn lawọn naa fẹẹ fidi iru iku to pa a mulẹ, boya loootọ ni wọn fẹẹ ṣe bẹ abi bẹẹ kọ, ijọba ni wọn o gbọdọ da a laṣa rara, tori ẹni to ba ṣe e, kele aa gbe tọhun ni.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ẹka idajọ naa, Abilekọ Grace Alọ, fi lede lorukọ ọga rẹ ti i ṣe Kọmiṣanna feto idajọ, Amofin agba Moyọsọrẹ Onigbanjo, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹta yii, lo ti ni, iwadii ijinlẹ ati ayẹwo ti awọn ọjọgbọn lati fasiti imọ iṣegun Lagos State University Teaching Hospital, ṣe si oku ti fihan pe ina mọnamọna lo gbe oloogbe yii to fi gbẹmi mi lojiji.

Wọn ni loootọ lawọn ko ti i ri iwe ibeere boya wọn fẹẹ hu oku naa lati tun ṣayẹwo si i lakọtun o, amọ ki ẹnikẹni to ba fẹẹ kọ iru iwe ibeere bẹẹ ma wulẹ ṣeyọnu mọ, tori esi ijọba ni pe ko saaye fun iru nnkan bẹẹ.

O ni iwadii to lọọrin ṣi n tẹsiwaju, awọn si n ṣiṣẹ nifọwọ-sowọpọ pẹlu awọn agbofinro gbogbo lati ri i pe, ẹlẹṣẹ kan ko lọ lai jiya lori iṣẹlẹ aburu naa.

Tẹẹ o ba gbagbe, ọkan ninu awọn obi akẹkọọ to doloogbe yii, Ọgbẹni Adeyẹmi Adeniran, lo pariwo si gbogbo ọmọ Naijiria pe ki wọn gba oun lori iku aitọjọ ti awọn alaṣẹ ileewe naa fi pa ọmọ oun obinrin, Whitney Adeniran, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Keji, ọdun yii.

Baba yii ni nnkan kan ko ṣe ọmọ naa to fi mura, ti ọkọ ileewe wọn si waa gbe e lọ sibi ti wọn ti n ṣe ayẹyẹ ere idaraya onile jile ti wọn n pe ni Inter house sport, eyi to waye ni Agege Stadium. Ṣugbọn lojiji ni wọn pe oun pe ọmọ naa ti ku. O ni aibikita ati ailaamojuto awọn alaṣẹ ileewe naa lo pa ọmọ yii, o waa bẹ awọn ọmọ Naijiria ki wọn ma jẹ ki iku ọmọ oun lọ bẹẹ.

Leave a Reply