Esi idibo aarẹ: Atiku ṣaaju awọn to ṣewọde lọ sọfiisi INEC

Faith Adebọla

Eruku nla lo n sọ lọwọ bayii niwaju ọfiisi apapọ ajọ eleto idibo ilẹ wa, Independent National Electoral Commission, INEC, l’Abuja, latari iwọde ati ifẹhonuhan kan ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, ṣagbatẹru rẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹta, ọdun yii, lori abajade esi idibo aarẹ to waye lọsẹ to kọja yii. Oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu naa, Alaaji Atiku Abubakar ati igbakeji rẹ, Ifeanyi Okowa, ni wọn lewaju awọn oluwọde naa.

Bakan naa ni adari igbimọ ipolongo ibo fun Atiku, to tun jẹ gomina ipinlẹ Sokoto, Aminu Tambuwal, ati alaga ẹgbẹ oṣelu naa, Sẹnetọ Iyorchia Ayu, awọn gomina kan lẹgbẹ PDP, atawọn agbaagba ẹgbẹ ti wọn jẹ ọmọ igbimọ aṣeefọkantan ẹgbẹ naa, Board of Trustee, wa lara awọn to ṣaaju.

Ọpọ awọn oluwọde naa ni wọn gbe oniruuru patako ati akọle ti wọn kọ ọrọ to fi aidunnu wọn han si, dani. Diẹ lara akọle naa ka pe: “INEC, ẹ ma lu dẹmokiresi yii pa o”, “INEC ti doju ifẹ-inu awọn araalu de o” “Ojooro nla ni eyi tẹ ẹ ṣe yii, ko le duro” “Idajọ ododo gbọdọ waye, esi awuruju ko tẹ wa lọrun” ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Lati nnkan bii kilomita meji si ọfiisi ajọ INEC eyi to wa ni Legacy House, lagbegbe Maitama, lolu-ilu ilẹ wa, Abuja lawọn ero rẹpẹtẹ naa ti n fẹsẹ rin bọ, ko si ṣee ṣe fawọn agbofinro lati di wọn lọwọ, titi ti wọn fi dewaju ọfiisi naa, nibi ti wọn duro si, wọn n kọrin loriṣiiriṣii, wọn si n sọrọ fatafata.

Titi kan awọn akanda ẹda ni wọn gun kẹkẹ wa, ọpọ de fila alawọ buluu ti wọn kọ akọle PDP ati orukọ ATIKU/OKOWA si, gẹgẹ bawọn aṣaaju wọn naa ṣe de e.

Titi dasiko ta a fi n ko iroyin yii jọ ni awọn ero ṣi n ya bii omi, ọkọ akẹru lo n ko wọn de.

Ṣe latigba ti wọn ti kede esi idibo sipo aarẹ, eyi to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ti wọn si kede lọjọ mẹrin lẹyin naa pe oludije lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, lo gbegba oroke, ni Atiku ati ẹgbẹ oṣelu PDP ti fariga pe awọn ko fara mọ ikede ti INEC ṣe.

Alaroye gbọ pe wọn ti gba ile-ẹjọ lọ lori ọrọ yii.

Leave a Reply