Ẹ woju awọn Fulani to n da awọn eeyan lọna ni Ṣaki

Olawale Ajao, Ibadan

Awọn ero to n ti Ṣaki lọ siluu Igboho lagbegbe Oke-Ogun, ni ipinlẹ Ọyọ, lọjọ Abamẹta, Satide, to lọ lọhun-un ko faraare dele. Awọn ọdọ Fulani mẹfa kan ti wọn dihamọra pẹlu ibọn, ada atawọn nnkan ija oloro mi-in lo ṣa wọn ladaa, ti wọn si tun ja wọn lole lọsan-an gangan.

Ọmọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (27) kan to n jẹ Abubakar Muhammed lo ṣaaju ikọ awọn adigunjale naa. Orukọ awọn yooku ni Umoru Abdullahi, ẹni ogun (20) ọdun; Muhammadu Bello, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn (34);  Alti Abubakar, ẹni ọdun mọkanlelogun (21); Abdullahi Muhammed, ọmọ ogun (20) ati Buba Sanni ti ko ju ọmọọdun mọkandinlogun (19) lọ ni tiẹ.

 

One thought on “Ẹ woju awọn Fulani to n da awọn eeyan lọna ni Ṣaki

Leave a Reply

%d bloggers like this: