Eedi ree o! Ẹdamisan yinbọn pa Jeremiah n’Irele, o ni ẹran ẹtu loun pe e

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Baba ẹni ọgọta ọdun kan, Ẹ̀dámísàn Ọwáìyàn, ni wọn ti wọ lọ sile-ẹjọ Majisireeti kin-in-ni to wa ninu ọgba Oke-Ẹda, niluu Akurẹ, lori yiyin ibọn lu ọdẹ ẹgbẹ rẹ kan ti wọn porukọ rẹ ni Jeremiah Oyenẹyin, ẹni ọdun marundinlogoji, ninu igbo ibi ti wọn ti n ṣọdẹ nitosi Ode-Irele, nipinlẹ Ondo.

Ninu ẹsun ti wọn ka si baba agbalagba naa lẹsẹ lasiko to foju bale-ẹjọ laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹjọ, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii pe o yinbọn pa Jeremiah, ninu oko kan ti wọn n pe ni Odò- Ẹ̀ríwà, eyi to wa lagbegbe Ìyánsan, nijọba ibilẹ Irele, ni nnkan bii aago mẹta aabọ oru ọjọ kejilelogun, oṣu Kejila, ọdun 2023 to kọja.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun, Agbefọba, Nelson Akintimẹhin, ni ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan olujẹjọ ta ko abala okoolelọọọdunrun din mẹrin (316) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006. Akintimẹhin ni ẹbẹ oun sile-ẹjọ ni pe ki adajọ paṣẹ pe ki wọn fi olujẹjọ ọhun pamọ sọgba ẹwọn titi di igba ti wọn yoo fi ri imọran gba lati ọfiisi ileeṣẹ to n gba adajọ nimọran.

Olujẹjọ ọhun ninu alaye diẹ to ṣe ki adajọ too gbe ipinnu rẹ kalẹ ni iṣẹ agbẹ loun yan laayo, ati pe lẹẹkọọkan tọwọ oun ba dilẹ diẹ loun maa n dẹ igbẹ ẹran pipa. O ni Oloogbe Jeremiah naa ki i ṣe ọdẹ rara, iṣẹ agbẹ lawọn jọ n ṣe, ti ọjọ si ti pẹ tawọn ti jọ maa dẹ igbẹ ẹran pipa papọ, bo tilẹ jẹ pe o kere si oun pupọ lọjọ ori.

O ni oun ko ni ija kankan pẹlu rẹ, bẹẹ lawọn ẹbi oloogbe funra wọn si le jẹrii si i pe ko si ede aiyede kankan rara laarin awọn.

Ẹdamisan ni Jeremiah funra rẹ lo ni oun fẹẹ tẹle oun lọọ ṣọdẹ loru ọjọ iṣẹlẹ naa, nitori o wu oun lati lọọ pa ẹran igbẹ fun iyawo oun, ki awọn le rí nnkan ṣe ọdun Keresimesi to n bọ lọna.

Inu igbo yìí lo ni awọn wa ti awọn fi ri ẹtu obeje kan nibi to ti n jẹ kiri, ti oun si sọ fun un pe ko duro sibi kan de oun ki oun fi tọpasẹ ẹranko naa lọ.

O ni laipẹ loun ri nnkan kan to n kọ mọna mọna lọọọkan bii oju ẹranko, ti oun ko si ronu lẹẹmeji ki oun too sina ibọn bo o, lai mọ pe Jeremiah ti kuro nibi ti oun ni ko duro si.

O ni dipo igbe ẹranko ti oun n reti, ariwo, ‘yee yee’ to jẹ ti eniyan loun n gbọ lẹyin ti oun yinbọn naa tan, leyii to mu ki oun mori le ọna ibi ti oun yinbọn si, ti oun si ba ẹnikeji oun ninu agbara ẹjẹ to n jẹ irora.

Ẹdamisan ni kiakia loun sare pada lọ si abule lati lọọ fohun to n ṣẹlẹ to awọn eeyan leti, lẹyin eyi lo ni oun lọ si teṣan ọlọpaa lati lọọ fa ara oun le awọn agbofinro lọwọ.

Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ Musa Al-Yunus ni ki wọn ṣi da olujẹjọ naa pada si teṣan titi di Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanla, oṣu Kin-in-ni yii.

Leave a Reply