Mathew yii ko lọrọọ gbọ o, ọjọ kẹta to jade lẹwọn lo tun lọọ jale

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọpọ awọn eeyan to wa nibi ti wọn ti n ṣafihan awọn afurasi ọdaran kan ni olu ileeṣẹ awọn ẹṣọ Amọtẹkun to wa ni Alagbaka, niluu Akurẹ, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹjọ, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii, ni wọn n wo ọmọkunrin kan ti wọn porukọ rẹ ni Mathew Simeon tiyanu tiyanu, nigba ti wọn gbọ iroyin itu buruku to ti pa ninu iṣẹ ole jija to yan laayo.

ALAROYE gbọ lati ẹnu afuarsi ẹni ọdun mọkanlelogun ọhun funra rẹ pe lati bii ọdun diẹ lo ti wa ninu ọgba ẹwọn Ṣegede, to wa niluu Ondo, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo, lori ẹsun ole jija ti wọn fi kan an nigba naa.

Ọjọ kin-in-ni, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 ta a wa yii, lọjọ ti wọn da fun un pe ko lo lọgba ẹwọn pe, to si gba itusilẹ ninu ọgba ẹwọn ti wọn ti i mọ. Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ fun gbogbo awọn ti wọn gbọ pe ọjọ kẹrin, oṣu yii kan naa, iyẹn lẹyin ọjọ mẹta pere to jade lẹwọn lo tun lọọ fọ awọn ṣọọbu mi-in l’Akurẹ, to si ji ọpọlọpọ ẹru ko lọ.

Ọkunrin ọmọ bibi ilu Abakaliki, ọhun lọwọ awọn ẹṣọ Amọtẹkun pada tẹ nibi to ti n gbiyanju ati ta lara awọn waya to ji ko ninu ṣọọbu oniṣọọbu to fọ.

Alakooso ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Akọgun Adetunji Adelẹyẹ ti ni awọn ko ni i pẹẹ wọ Mathew lọ sile-ẹjọ lati lọọ sọ tẹnu rẹ lẹyin ti iwadii ba pari lori ẹsun ti wọn fi kan an.

 

Leave a Reply