Ọlawale Ajao
Inu holahilo lawọn olugbe ilu ti wọn n pe ni Boko, nipinlẹ Plateau, wa bayii, pẹlu bi ibinu ṣe gbe awọn obinrin ilu naa wọ bii ẹwu, ti wọn si dana sun ile ọba wọn lasiko ti wọn fẹhonu han lọ saafin.
Ọlọrun paapaa lo yọ ori ade naa, Ọba Saf Adanchin, funra rẹ ninu ikọlu ọhun to waye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ karun-un, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii, nitori awọn eeyan naa ko kọ bi kabiesi ba le jona mọle, ko jona mọle.
Ifẹhonuhan awọn abiamọ aye ọhun, pẹlu awọn ọdọ diẹ to wa laarin wọn, lo waye nitori bi awọn agbofinro ṣe mu awọn ọmọ ilu naa sọ satimọle latari ifẹhonuhan kan ti wọn ti kọkọ ṣe ṣaaju lori ikọlu to maa n waye niluu naa gbọnmọgbọnmọ, eyi to ti ran ẹgbẹẹgbẹrun eeyan lọ sọrun apapandodo, ti ọpọ ninu awọn obinrin wọnyi si ti di opo ojiji, ti awọn ọmọ wọn paapaa ti di alaini baba laye mọ.
Ṣaaju, lọjọ Jimọ yii kan naa ni wọn ti kọkọ fẹhonu han lọ si agọ ọlọpaa to wa nigboro ilu naa pẹlu ọfiisi ikọ eleto aabo ijọba ti wọn n pe ni Safe Heaven, to jẹ tijọba ipinlẹ Plateau, to wa ninu ilu naa.
Nigba ti ẹgbẹ awọn ọdọ ilu Bokko, to n ri si eto idagbasoke ilu naa n sọrọ lori iṣẹlẹ yii, wọn ni ohun to n bi awọn araalu naa ninu, to si fa ifẹhonuhan lọtun-un losi yii ko ṣẹyin bi awọn ṣọja ti wọn ko wa sinu ilu naa lati waa dẹkun idarudapọ to n waye nibẹ ṣe n gbe lẹyin awọn ọdaran, ti wọn s n fiya jẹ awọn araalu gan-an to yẹ kí wọn máa dáàbò bo.
Ikọlu ti awọn janduku agbebọn ṣe ninu ilu naa lọjọ meji ṣaaju ọjọ ọdun Keresi to kọja yii lo jẹ eyi to buru ju lọ lẹnu lọọlọọ yii, nitori bi wọn ṣe pa aimọye eeyan ni wọn dana sun ọpọlọpọ ile.
Gẹgẹ bi ẹgbẹ awọn ọdọ naa ṣe sọ ninu
atẹjade ti wọn fi ṣọwọ sawọn oniroyin lori iṣẹlẹ yii, “pẹlu ọgbẹ ọkan la fi kọ iwe yii, nítorí awọn ṣọja to yẹ ki wọn maa daabo bo wa gan-an ni wọn tun n fiya jẹ wa.
“Latigba ti awọn janduku ti kọ lu ilu yii lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kejila, ọdun to kọja, lawa ọdọ ilu yii ko ti gbadun mọ, nitori lojoojumọ lawọn ṣọja n ti wa mọlẹ, ti ọpọ eeyan si n fara pa nibi ti wọn ti n sa fawọn soja.
Igbakeji Aarẹ orileede yii, Sẹnetọ Kashim Shettima, ti ṣabẹwo siluu Bokko, o si rọ awọn araalu naa lati ma ṣe fi ara wọn sílẹ fun eṣu nipa gbigbẹsan iya to n jẹ wọn lara ẹnikẹni.
Aarẹ orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, funra rẹ ti dara pọ mọ ọgọọrọ eeyan agbaye ti wọn bu ẹnu atẹ lu awọn ikọlu to n waye lemọlemọ ninu ilu yii, ati ni ipinlẹ Plateau lapapọ.
Tinubu waa paṣẹ fawọn agbofinro lati ṣewadii nipa awọn ikọlu naa, ki wọn si wọna bi opin yoo ṣe de ba a kiakia.