Awọn agbebọn to ji baba atawọn ọmọ ẹ mẹfa gbe n beere fun ọgọta miliọnu Naira 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Inu wahala ati aibalẹ ọkan ni mọlẹbi kan lagboole Sokoto, Òkèkere, niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara, wa bayii. Ohun to fa a ti ọkan wọn fi gbọgbẹ gidi ko ju bi awọn olubi ẹda agbebọn ṣe lọọ ka awọn  ọmọ wọn kan mọle, wọn yinbọn pa aburo, Abdufatai Al-kadriyar, wọn ji ẹgbọn, Alaaji Mansoor atawọn ọmọ rẹ mẹfa gbe lọ, ti wọn si ti n beere fun ọgọta miliọnu Naira gẹgẹ bii owo itusilẹ bayii.

ALAROYE, gbọ pe alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keji, oṣu Kin-in-ni yii, lawọn agbebọn kan ti wọn dihamọra pẹlu ibọn ati awọn ohun ija oloro miiran ya bo ileegbe Alaaji Mansoor Al-kadriyar, niluu Abuja, wọn ji oun atawọn ọmọ rẹ mẹfẹẹfa gbe lọ, awọn agbebọn ọhun ko ri iyawo nibi to fara pamọ si. Ni kete ti wọn lọ tan ni iyawo pe aburo ọkọ rẹ, iyẹn Abdulfatal, pe awọn ajinigbe ti waa ji ẹgbọn rẹ atawọn ọmọ rẹ mẹfẹẹfa gbe lọ, ṣugbọn nibi ti Abdufatai ti jade lati doola ẹgbọn rẹ ni wọn ti yinbọn fun un, to si ku lẹṣẹ kẹṣẹ.

Ni bayii, awọn agbebọn naa ti tu baba, iyẹn Alaaji Mansoor silẹ, ti wọn si ni ko lọọ wa ọgọta miliọnu (60m) wa lati fi doola awọn ọmọ rẹ.

Gbogbo mọlẹbi agboole Sokoto, Masingba, Òkèkere, niluu Ilọrin, ti waa n beere fun iranwọ gbogbo awọn ẹlẹyinju aanu atawọn tori ṣẹgi ọla fun ki wọn ran wọn lọwọ lati ri ọgọta miliọnu Naira ko too di ọjọ Ẹti, Furaide, ọjọ kejila, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ti wọn da fun wọn.

Ẹni to jẹ baba fun tẹgbọn-taburo yii, Al-kadriyar Sherifdeen, lo gbe kinni ọhun sori ayelujara lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ karun-un, oṣu Kin-in-ni yii, nibi to ti ni ibanujẹ ọkan ni bi awọn ṣe padanu ẹmi Abdufatai ṣọwọ awọn agbebọn, tawọn si n reti ki wọn tu ọmọ mẹfẹẹfa kalẹ kuro lakata wọn.

O ni, awọn agbebọn ni kawọn tete wa owo kiakia, ko too di ọjọ Ẹti, Furaide, ọjọ kejila, oṣu yii.

Leave a Reply