Nitori ọrọ ti ko to nnkan, ayalegbe lu lanlọọdu rẹ daku

Adewale Adeoye
Iwaju Onidaajọ Abubakar Sadiq, tile-ẹjọ kan to wa lagbegbe Kabusa, ‘Grade 1 Area Court, to wa niluu Abuja, ti i ṣe olu ilu ilẹ wa ni wọn foju Ọgbẹni Chris Okoye, ẹni ọdun mẹrinlelogoji kan ba. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o lu lanlọọdu rẹ ni alubami, o si pọ debii pe ọsibitu lo gba lanlọọdu ọhun silẹ lọwọ iku ojiji.
ALAROYE gbọ pe ọrọ ti ko to nnkan kan lo ṣẹlẹ laarin baba onile yii ati ayalegbe rẹ ti wọn jọ n gbe l’Ojule keji, Opopona Niger Nova, ni Apo, ṣugbọn eyi ti Chris ti i ṣe ayalegbe iba fi ṣe suuru pẹlu baba onile rẹ, ṣe lo mu un lu, to si lu u bajẹ ko too di pe awọn kan sare gba baba ọhun silẹ lọwọ rẹ lọjọ yii.
Ọlọpaa olupẹjọ, O.S Ọsho, to foju olujẹjọ bale-ẹjọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ karun-un, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii, sọ nile-ẹjọ ọhun pe, ‘Oluwa mi, ọjọ kẹta, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ni Ọgbẹni Chris hu iwa ọdaran ọhun si lanlọọdu rẹ ti wọn jọ n gbele papọ. Lẹyin ti Chris lu baba onile rẹ daadaa tan ni baba ọhun lọọ fẹjọ sun awọn ọlọpaa agbegbe naa, tawọn yẹn sí lọọ fọwọ ofin mu un nile rẹ. Teṣan awọn agbofinro ni Chris ti jẹwọ pe loootọ loun huwa naa, ṣugbọn eṣu lo gbọwọ oun lo lasiko toun atawọn ọmọ rẹ meji kan tawọn ọlọpaa lawọn n wa bayii ti wọn jọ dawọ jọ lu baba onile wọn gidi’.
Gbogbo iwa palapala ti Chris hu yii pata ni olupẹjọ sọ pe ki i ṣe ohun to daa, ti ijiya nla si wa fẹni to ba ṣe bẹẹ, o si tọka si abala ofin kan lati gbe ọrọ rẹ lẹsẹ.
Ninu ọrọ rẹ, olujẹjọ ni oun ko jẹbi pẹlu alaye.
Adajọ ni ki wọn lọọ ju Chris sẹwọn titi di ọjọ kẹrindinlogun, oṣu yii, tawọn ọlọpaa fi maa ri awọn ọmọ Chris ti wọn jọ huwa laabi ọhun mu.
 

Leave a Reply