O ṣẹlẹ, David ti gba ibi to gba waye pada sọhun-un, oogun ale to lo lati ba ololufẹ rẹ sun lo yiwọ

Adewale Adeoye

Owo ti ada mọ ti i ka a leyin ti ṣe bẹẹ ka ọmọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ David Mguni leyin pẹlu bo ṣe ku iku ojiji nitori bo ṣe lọọ ra oogun ale lọdọ oniṣẹgun ibilẹ kan lati fi ba ale rẹ lo pọ. Oogun ọhun lo gbodi lara rẹ ti ẹlẹkọ ọrun fi polowo fun un.

Aipe yii ni ọmọkunrin ẹni ọdun mejilelogun to n gbe lagbegbe Jeremiah, lorile-ede Zimbabwe, ọhun lọọ ba onisẹgun ibilẹ kan lati ra oogun ibilẹ ti wọn n pe ni ale, eyi ti ko ni i mu nnkan ọmọkunrin rẹ walẹ bọrọ to ba wa lori obinrin. Wọn ni o ti ṣe diẹ ti ololufẹ rẹ kan ti n dajọ fun un pe oun maa waa sun lọdọ rẹ, ṣugbọn ti ki i mu adehun rẹ ṣẹ. Ṣugbọn nigba ti ẹri gidi wa lọsẹ yii pe ololufẹ ọhun n bọ ni oloogbe naa ba lọọ ra oogun ale, ko ba a le raaye kona bo o daadaa bo ba de. Gbogbo alaye ti wọn ni oniṣẹgun ibilẹ ọhun ṣe fun un nipa bi yoo ṣe lo oogun ọhun ni wọn ni oloogbe ọhun tẹle, ṣugbọn nnkan yiwọ fun un lẹyin to lo oogun naa tan. Ara rẹ ko balẹ mọ,  bẹẹ lo n laagun kikan-kikan. Kawọn eeyan si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, ẹlẹkọ ọrun ti n polowo fun un. Ko si pẹ rara to fi ṣubu lulẹ gbalaja ninu ile rẹ, to si ku patapata.

Nigba tawọn araale rẹ maa fi gbe e de ileewosan, awọn dokita sọ fawọn to gbe e wa pe oku rẹ ni wọn gbe wa. Beba oogun ti oloogbe naa lo ku lawọn araale rẹ ri ti wọn fi mọ pe aṣilo oogun ale ti ọhun lo ṣokunfa iku ojiji to pa a. Bayi ni David para rẹ nitori yinkunyinkun to fẹe gbadun lara obinrin.

Leave a Reply