O ma ṣe o, wọn si pa ọmọ Naijiria to n kẹkọọ niluu oyinbo yii nipa oro

Adewale Adeoye

Titi di akoko taa n ko iroyin yii jọ, inu ọfọ ati ironu nla gbaa ni ẹbi, ara ati ojulumọ Oloogbe Afọlabi Stephen Opaso, ẹni ọdun mọkandinlogun kan to jẹ ọmọ orile-ede Naijiria, to n kẹkọọ nilẹ Gẹẹsi wa bayii. Ko sohun meji ti wọn fi wa ninu ipayinkeke ọhun ju pe ṣe ni ọlọpaa ilu kan ti wọn n pe ni Winnipeg, lorile-ede Scotland, yinbọn lu u, to si ku patapata ko too di pe wọn gbe e deleewosan rara. Iṣẹlẹ ọhun waye lọjọ aisun ọdun tuntun to kọja yii, nitori ọrọ ti ko to nnkan.

ALAROYE gbọ pe aipẹ yii ni oloogbe ọhun gbera kuro lorile-ede wa, to si lọ silẹ Gẹẹsi ọhun lati lọọ kẹkọọ kun ẹkọ rẹ, ẹkọ eto ọrọ aje kan lo n kọ lọwọ nileewe Manitoba, lorile-ede naa ko too di pade iku ojiji  lọwọ ọlọpaa kan niluu naa.

Awọn kan ti oloogbe ọhun n gbe lọdọ wọn lagbegbe Winnipeg, ni wọn sare pe ọlọpaa agbegbe naa lori foonu nigba ti wọn ri i pe oloogbe n ṣe bakan-bakan, wọn ni ọrọ ẹnu rẹ ko jọ ti ẹni tori rẹ pe rara mọ, ati pe ṣe lo tun mu ọbẹ oloju meji kan dani, to si fi n dẹruba wọn ninu ile lọjọ naa. Kọrọ wọn ma baa ja si abamọ ni wọn ṣe sare pe ọlọpaa lori foonu, tawọn yẹn si tete de lati waa fọwọ ofin mu un lọ sagọọ wọn ki wọn le bi i leere  ohun to ṣẹlẹ to fi n f’ọbẹ ọwọ rẹ halẹ mọ awọn ọrẹ rẹ yii ninu ile.

Ọga ọlọpaa agbegbe Winnipeg, nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye, Ọgbẹni Danny Smyth, sọ fawọn oniroyin pe gbara tawọn ọlọpaa debẹ ni wọn ba oloogbe yii atawọn ọrẹ rẹ meji kan ninu ile, wọn ko le jade sita nitori ti oloogbe n fi ọbẹ aṣooro ọwọ rẹ halẹ mọ wọn. Gbogbo akitiyan awọn agbofinro lati gba ọbẹ ọwọ rẹ yii lo ja si pabo, nigba to tun ya ni oloogbe ọhun ba tun kọju si awọn ọlọpaa naa, ko ma baa fi ọbẹ ọwọ rẹ ṣe awọn yẹn leṣe ni wọn ba kuku yinbọn lu u, ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe ibi ti ko ti daa ni ọta ibọn ọhun ti ba a, to si ku patapata ko too di pe wọn gbe e de ọsibitu ijọba agbegbe naa. Awọn dokita ti wọn ba lẹnu iṣẹ lọjọ naa sọ pe apọju ẹjẹ to jade lara oloogbe lo ṣokunfa iku ojiji ọhun fun un.

Ṣao awọn ọrẹ oloogbe naa ni gan-an-gan-an-gan ti oloogbe naa maa n ṣe ki i ṣe ajoji sawọn rara, ṣugbọn awọn pe ọlọpaa  lati waa ran an lọwọ gẹgẹ bii ohun to nilo lasiko naa ni, o waa ṣe ni laaanu pe awọn ọlọpaa naa yinbọn lu u, to si ku patapata. Wọn tiẹ tun fi kun un pe ki i ṣe pe oloogbe naa koju ija sawọn ọlọpaa ọhun rara ko too di pe wọn yinbọn pa.

Ni bayii, awọn ẹbi oloogbe ọhun kọọkan ti wọn n gbe niluu naa ti lawọn maa pe awọn ọlọpaa orile-ede ọhun lẹjọ lori bi wọn ṣe yinbọn lu ọmọ awọn lai jẹ pe o doju ija kọ wọn.

Wọn ni ipe fun iranlọwọ lasan fẹni to larun ọpọlọ ni wọn pe awọn ọlọpaa ọhun, o ṣe waa jẹ pe wọn maa yinbọn pa a.

Leave a Reply