Tinubu kọ lẹta si Funkẹ Akindele, eyi lohun to wa ninu rẹ

Adewale Adeoye

Bi ọmọ ẹni ba daa ka sọ, ki i ṣe ka fi ṣ’aya, ọmọ ẹni ko si le ṣe idi bẹbẹrẹ ka fi ilẹkẹ si idi ọmọ ẹlomi-in gẹgẹ bi owe Yoruba. Eyi lo fa a ti Aarẹ orileede Naijiria, Aṣiwaju Bọla Tinubu, fi kọwe ikini ku oriire ranṣẹ si ọkan ninu awọn to mọ tifun tẹdọ ere tiata nilẹ wa, Olufunkẹ Akindele, ti gbogbo eeyan tun maa n pe ni Jenifa tabi Lefty.

Lẹta ti Tinubu kọ ko sẹyin aṣeyọrin ti obinrin ti wọn tun maa n pe ni Iya ibeji naa ṣe ninu fiimu rẹ to ṣẹṣẹ gbe jade ti wọn n wo kaakiri ile sinima lorileede yii bayii, eyi to pe ni Ẹya Judah (The Tribe of Judah). Iṣẹ nla ati ọgbọn atinuda to tayọ ti oṣere to ti gbe fiimu oriṣiiriṣii jade naa ṣe sinu eyi ti wọn pe ni The Tribe of Judah yii lo mu ki fiimu naa tayọ ju gbogbo awọn ojugba rẹ lọ. Laarin ka diju ka la a, fiimu naa lo si n ṣe daadaa ju ninu eyi ti wọn ti n gbe jade ninu itan ere ṣiṣẹ ni orileede Naijiria.

Itan nla ni Funkẹ fi balẹ pẹlu bo ṣe jẹ pe ninu agbelewọn ti wọn maa n wo lati fi wo bi fiimu kan ṣe kun oju oṣuwọn si, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni (box-office), fiimu ọmọ bibi ilu Ikorodu, nipinlẹ Eko yii, lo ta gbogbo wọn yọ. Ninu ohun ti awọn to maa n ṣe agbelewọn yii maa n wo ni bi awọn eeyan ṣe tu jade lati ra tikẹẹti lati fi wo ere naa si ati bi okiki ere ọhun tabi awọn to kopa ninu rẹ ṣe gbilẹ daadaa. Ni ti fiimu Funkẹ Akindele to wa nita bayii, biliọnu kan Naira ni owo ti wọn ti pa lapapọ, bo tilẹ jẹ pe ninu eyi ni wọn yoo ti yọ gbogbo owo ti wọn fi ṣe fiimu ọhun ati eyi ti wọn lo fun ipolongo rẹ atawọn inawo mi-in.

Ta a ba sọ pe Funkẹ ni ọmọ ti wọn n sọ lọwọlọwọ bayii lagboole tiata, ki i ṣe asọdun rara, nitori igba akọkọ niyi ninu itan fiimu nilẹ wa ti ere kan yoo pa biliọnu kan Naira. Pẹlu ẹ naa, owo yii ko ti i duro, nitori niṣe ni awọn eeyan n tu jade lati wo fiimu naa, bẹẹ lawọn ti wọn n gbọ okiki bo ṣe ṣe daadaa si naa n mura ati wo o, wọn fẹẹ mọ ara ti Funkẹ da sinu ere naa to fi di itẹwọgba kari aye, tori ki i ṣe Naijiria nikan ni wọn ti n royin rẹ.

Aṣeyọri oṣere to ti figba kan dupo igbakeji gomina ipinlẹ Eko yii lo mu ki Aarẹ Tinubu kọ lẹta si i lati ki i ku oriire fun bi fiimu rẹ tuntun, (The Tribe of Judah), Ẹya Judah, ṣe n ṣe daadaa lori atẹ agbaye bayii.

Ninu atẹjade kan ti Oludari eto iroyin fun Tinubu, Ọgbẹni Ajuri Ngelale, fi sita eyi, ti Aarẹ funra rẹ fọwọ si l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii, lo ti sapejuwe oṣerebirin onitiata ọhun gẹgẹ bii ẹnikan to kunju oṣunwọn gidi laarin awọn ẹlẹgbẹ rẹ, to si n ṣe daadaa nidii iṣẹ tiata to yan laayo bayii. Aarẹ gboṣuba nla fun un fun ipa pataki ti oṣerebirin naa ko lori ere tiata ilẹ wa, eyi to jẹ ki awọn oyinbo alawọ funfun ko fi le ko iyan wa kere lasiko yii mọ.

Tinubu tun lu awọn ọmọ orilẹ-ede yii lọgọ ẹnu fun bi wọn ṣe n gbiyanju gidi lati tayọ ninu gbogbo bi nnkan ko ṣe lọọ deede fun wọn lasiko yii, to si ni ọjọ iwaju awọn ọdọ orile-ede yii daa gidi pẹlu bi wọn ṣe n ṣe daadaa ninu gbogbo ohun ti wọn ba dawọ le.

Aarẹ waa ṣeleri ayọ fawọn ọdọ orile-ede yii pe iṣakoso ijọba oun maa sa gbogbo ipa rẹ lati ri i pe oun ṣe ohun gidi fun ẹka aṣa ati iṣẹ ilẹ wa, paapaa ju lọ awọn oṣere to n gbe fiimu jade lati le jẹ ki iṣẹ ti wọn yan laayo ọhun fẹsẹ mulẹ daadaa, ki wọn si gberu si i.

Yatọ si Aarẹ orile-ede yii too ti ki Funkẹ Akindele lori bi fiimu rẹ ṣe n ṣe daadaa si lori atẹ ọja agbaye lọwọ bayii, Alhaji Aiku Abubakar to dije dupo aarẹ orile-ede wa lasiko ibo ọdun to kọja yii naa ba Funkẹ Akindele yọ  lori aṣeyọri yii. Atiku ni ki i ṣe asọdun rara pe awọn ọmọ orile-ede Naijiria ki i ṣe ẹni ti wọn le fọwọ rọ sẹyin rara ninu ohunkohun nilẹ yii ati l’Oke-Okun.

Atiku sọrọ ọhun di mimọ lori ayelujara lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ karun-un, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii. O ni fiimu Ẹya Judah yii ki i ṣe fiimu lasan, ṣugbọn eyi to fi bi awọn oṣere tiata ilẹ wa ṣe kunju oṣunwọn to han ni, nitori pe fiimu ọhun kun fun oniruuru ọgbọn ati ẹkọ.

Atẹjade ọhun ti Atiku fi sita lọ ti sọ pe, ‘‘Akọ iṣẹ ti ko lafiwe rara ni fiimu Ẹya Judah yii jẹ, o fi han gbangba pe Ọlọrun Ọba jogun ọpọlọ pipe fawọn araalu orile-ede yii, fiimu ọhun si tun fi han pe Funkẹ Akindele ki i ṣe ọjẹ wẹwẹ rara ninu iṣẹ to yan laayo, yii nitori nipasẹ fiimu rẹ, o ti gbe orile-ede wa si gbagede to daa bayii. Apẹẹrẹ rere to fi lelẹ ko lẹgbẹ rara. Atiku ni Funkẹ Akindele to dije gẹgẹ bii igbakeji gomina ninu ibo to waye gbẹyin nipinlẹ Eko lorukọ ẹgbẹ oṣelu PDP jẹ ẹni to kunju oṣunwọn ninu ohun gbogbo.

O ni, ‘Mo ki Funkẹ Akindele fun ti aṣeyọri to ṣe ninu fiimu rẹ to pe ni Ẹya Judah yii, o fi han gbangba pe ojulowo oṣerebirin onitiata ni, ko rọrun rara ki fiimu ọmọ ilẹ Adulawọ gba ori atẹ agbaye kan bii fiimu Ẹya Judah ti Funkẹ Akindele ṣẹṣẹ gbe jade yii, o ti fi han pe ọlọpọlọ pipe ni, o si kunju oṣunwọn ninu ohun gbogbo bayii, orileede wa ati ẹgbẹ oṣelu PDP paapaa n mu ẹ yangan bayii, o ku oriire.

Leave a Reply