Gbese ree o, ijọba gba ọja lori awọn to n taja loju titi l’Ekoo, ni wọn ba bu sẹkun

Faith Adebọla

Tẹkun-tomije lawọn ontaja kan ti wọn ṣe kongẹ awọn ẹṣọ amunifọba to n ri si ọrọ ayika l’Ekoo, iyẹn awọn ẹṣọ Kick Against Indiscipline, KAI, ati ti Lagos State Environmental Safety Commission, LAGESC, fi n rawọ ẹbẹ sawọn agbofinro naa pe ki wọn ṣaaanu awọn, ki wọn maṣe dina atijẹ atimu awọn, amọ niṣe lawọn ẹṣọ naa n rọ ọja wọn da sinu ọkọ, ti wọn si n faṣẹ ọba mu wọn, wọn lawọn ontaja naa rufin ọja tita leti titi.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ karun-un, oṣu Kinni, ọdun 2024, yii ẹṣọ amuṣẹya ọhun, ti wọn n pe ni Taskforce, bẹ sigboro, lagbegbe Agege Motor Road, titi de Old Secretariat, ati GRA Ikeja, wọn si ko ṣibaṣibo ba awọn ọlọja to p’atẹ s’eti ọna, atawọn to gbe ọja leri ti wọn n kiri, bi wọn ṣe n le wọn mu, ni wọn ko ọja wọn, wọn n rọ ọ da sinu ọkọ ti wọn fi n ko awọn ọdaran ti wọn gbe wa, bẹẹ lawọn ọlọja naa n sunkun yọbọ.

Ninu atẹjade kan ti Kọmiṣanna lori ọrọ ayika ati ipese omi l’Ekoo, Ọnarebu Tokunbọ Wahab, fi soju opo ayelujara rẹ lori iṣẹlẹ yii, o ni “A o ni i fi ṣoju aanu lori ọrọ irufin. A ti ṣekilọ leralera fawọn ontaja yii pe ki wọn yee patẹ ọja wọn sawọn opopona tawọn eeyan n gba kọja, tabi awọn aaye to wa lẹgbẹẹ titi. Niṣe ni aṣa naa n dọti ilu Eko, ati pe o n fẹmi awọn eeyan sinu ewu, ṣugbọn wọn ko gbọ.”

Kọmiṣanna naa ni awọn oṣiṣẹ Taskforce yii fipa le awọn ọlọja ọhun ṣiaṣia ni agbegbe Alausa Secretariat, Agidingbi, Jakande Road, Iyana to lọ si teṣan LTV8, Ojodu Berger, ọna Fagba, ati ni Agege motor way.

Ninu ọkan lara awọn fidio to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara lori iṣẹlẹ yii, wọn ṣafihan bawọn ọlọja naa ṣe n tara aje, ti wọn n sunkun kikoro, bẹẹ lawọn ẹṣọ Taskforce ọhun ko wo wọn lẹẹmeji, niṣe wọn wọn n fọ kanta ọja wọn, ti wọn n rọ ọja naa da sinu ọkọ, ti wọn si n le awọn ontaja yii lere.

Kọmiṣanna Wahab ni ilu ti ko sofin ni ẹṣẹ ko si, ati pe awọn oṣiṣẹ oun ko ni i sinmi titi tawọn ontaja gbogbo yoo fi pa aṣẹ ijọba Eko mọ.

Oriṣiiriṣii ọrọ lawọn eeyan to ri iṣẹlẹ yii ti sọ, bawọn kan ṣe n bẹnu atẹ lu ijọba fun ọwọ lile ti wọn fi n mu awọn ọlọja yii, lairo ti ọwọngogo ọja ati iṣoro airowona ti ko mu ko ṣee ṣe fun ọpọ ninu wọn lati gba ṣọọbu, to si pọn dandan fun wọn lati gbọ bukaata, bẹẹ lawọn mi in n gboṣuba fun ijọba pe ohun ti wọn ṣe lo daa, tori ati dena ewu ijamba ọkọ to le ṣẹlẹ lẹgbẹ titi tawọn ọlọja naa n patẹ si.

Leave a Reply