Wọn ti gbe oku Akeredolu de si Naijiria, awọn mọlẹbi ẹ bara jẹ gidigidi

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

 Oku Gomina ana nipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu, ni wọn ti gbe wale lati orilẹ-ede Germany to ku si l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2023 to kọja. 

 Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, oku Aketi lo balẹ si papakọ ofurufu kan niluu Eko ni nnkan bii aago mẹta aabọ ọsan ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ karun-un, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024, ta a wa yii, iyẹn lẹyin ọjọ mẹwaa gbako to ti ku. 

 Lara awọn to lọọ tẹwọ  gba oku Arakunrin lasiko to balẹ si papakọ ofurufu yii ni iyawo rẹ, Arabinrin Betty Anyanwu Akeredolu, awọn ọmọ rẹ, awọn ẹbi rẹ ti Ọjọgbọn Wọle Akeredolu ko sodi, aṣoju Gomina ipinlẹ Eko, Ogun, Ọṣun atawọn agbaagba ninu ẹgbẹ All Progressive Congress nipinlẹ Ondo, ninu eyi ti Ade Adetimẹhin to jẹ alaga ẹgbẹ, Abilekọ Ọladunni Odu, ti i ṣe akọwe ijọba ipinlẹ Ondo, awọn aṣofin atawọn ọmọ igbimọ aṣejọba wa. 

 Awọn to wa nikalẹ lasiko ti wọn n sọ oku Aketi kalẹ lati inu baluu la gbọ pe wọn ko le pa ibanujẹ wọn mọra pẹlu bi pupọ ninu wọn ṣe bara jẹ gidigidi ti wọn si n ṣomi loju poroporo lai fi ibi ti wọn wa ṣe. 

 Wọn ni mọsuari kan niluu Eko ni wọn si gbe oku rẹ pamọ si titi di asiko ti wọn yoo fi ṣẹyẹ ikẹyin fun un. 

Leave a Reply