Lẹyin iku Akeredolu, wahala n bọ ninu ẹgbẹ APC Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Asiko yii kii ṣe eyi to rọrun rara fun igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress, ti ipinlẹ Ondo, niṣe ni ibẹru si gba ọkan wọn lori ahesọ kan ti wọn n gbọ pe o ṣee ṣe ki wọn yẹ aga mọ ọpọ awọn oloye ẹgbẹ ọhun nidii nipa bi wọn ṣe lawọn eeyan kan n gbero lati tu igbimọ apaṣẹ naa ka.

Ahesọ ti wọn n gbọ yii lo ṣokunfa bi ẹgbẹ kan ti wọn pe ara wọn ni ‘Ondo Elite’ ṣe jade lati kegbajare, ti wọn si n kilọ fawọn ti wọn n gbero yii lati tete jawọ ninu rẹ, nitori akoba nla to le ṣe fun ẹgbẹ oṣelu APC ninu eto idibo to n bọ ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2024, ta a wa ninu rẹ yii.

Ẹgbẹ Elite ninu atẹjade kan ti wọn fi sita lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ karun-un, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, nipasẹ akọwe wọn, Ọgbẹni Yẹmi Ọladiran, ni ẹbẹ lawọn n bẹ Gomina ipinlẹ Ondo, Ọnarebu Lucky Ayedatiwa, lati ko gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ mọra, ko si ri i daju pe alaafia oun iṣọkan tubọ fẹsẹ mulẹ laarin wọn, dipo gbigbe igbesẹ lati tu igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ ka.

Ọladiran ni ko si ani-ani pe ibẹru ti wa lọkan pupọ awọn ọmọ ẹgbẹ APC nipinlẹ Ondo, lori ohun ti wọn n gbọ pe awọn kan ti n mura lati yẹ aga mọ awọn oloye ti wọn n ṣakoso lọwọ nidii, ki wọn si yan awọn mi-in rọpo, ki aaye le gba awọn oludije to jẹ aayo wọn lasiko eto idibo gomina to n bọ lọna, bo tilẹ jẹ pe gbogbo ọna lofin ẹgbẹ fi ta ko igbesẹ ti wọn fẹẹ gbe ọhun.

O ni afaimọ kọrọ awọn ma yọri si ohun to sẹlẹ nipinlẹ Zamfara lasiko eto idibo gbogbogboo to kọja, nibi ti ẹgbẹ Peoples Democratic Party to jẹ ẹgbẹ alatako ti gba ipinlẹ naa mọ ẹgbẹ APC lọwọ nitori ede aiyede to wa laarin wọn.

Akọwe ẹgbẹ yii ni ko yẹ ki Ayedatiwa dori ipo tan ko waa gbagbe ibi ti Aarẹ Bọla Tinubu ba wọn pari ọrọ si nigba ti Rotimi Akeredolu ṣi wa laye, nitori bi oju ba yẹ oju, ki adehun ma ṣe yẹ rara.

O ni awọn ọmọ ẹgbẹ ṣi nigbagbọ kikun ninu Ade Adetimẹhin, to n dari awọn lọwọlọwọ nitori ọpọlọpọ aṣeyọri ati idagbasoke to ti de ba ẹgbẹ APC nipinlẹ Ondo labẹ iṣakoso rẹ, ati pe ki i ṣe asiko yii lo yẹ ki awọn eeyan kan ṣẹṣẹ maa gbero lati da nnkan ru mọ ọn lọwọ, nigba ti ko ni ju bii ọdun meji pere lọ to ṣi fẹẹ lo.

O waa rọ Ayedatiwa lati  ko gbogbo ọmọ ẹgbẹ mọra pẹlu bi eto idibo abẹle ṣe ku si dẹdẹ, nitori ohun ti yoo koba ẹgbẹ awọn ni, ti ẹnikẹni ba lọọ gbe igbesẹ lati tu ile ka lasiko yii.

Alukoro ẹgbẹ APC, Alex Kalẹjaye, sọ ninu ọrọ tirẹ pe ala ti ko le ṣẹ ni kawọn eeyan kan maa gbero lati tu igbimọ ẹgbẹ ka lasiko yii, niwọn igba ti ko si ede aiyede tabi rogbodiyan laarin awọn ọmọ ẹgbẹ.

Latigba ti wọn ti bura fun Ayedatiwa gẹgẹ bii gomina lẹyin iku ọga rẹ, Rotimi Akeredolu, lara ko ti rọ okun, ti ko si tun rọ adiyẹ mọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Ondo. Eyi ko sẹyin wahala to ti n waye sẹyin laarin ọmọlẹyin Aketi ati Ayedatiwa.

Ki i ṣe awọn oloye ẹgbẹ APC ti wọn jẹ oloootọ si Aketi nikan lọkan wọn ko balẹ rara latigba ti eeku ida iṣakoso ti bọ sọwọ Aiyedatiwa, pupọ ninu awọn kọmiṣanna atawọn ọmọ igbimọ aṣejọba gomina tẹlẹ ọhun lọkan tiwọn naa ko lelẹ, inu fuu, pẹlu ibẹru bojo ni wọn si fi n ṣe ohun gbogbo ti wọn n ṣe labẹ iṣakoso ti wọn ti n ṣiṣẹ lọwọlọwọ yii.

 

Leave a Reply