Ilẹ n jẹẹyan! Ọlọfana ti wọ kaa ilẹ lọ, awọn eeyan bara jẹ gidigidi  nibi isinku ẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ko si bi eeyan ẹni ṣe le dagba dagba to laye ti tọhun maa fẹ ko lọ, ka ma ti i sọ ẹni ti tọmọde tagba fẹran, to si jẹ ẹni ti wọn maa n fẹẹ maa ri lẹgbẹẹ wọn nigba gbogbo. Eyi lo fa a ti ọpọ eeyan fi bara jẹ nigba ti awọn aafaa kirun si gbajumọ onitiata ti ede Yoruba da lẹnu rẹ ṣaka nni, Adedeji Aderẹmi, ti gbogbo eeyan mọ si Ọlọfana lara tan, ti wọn si n gbe oku rẹ wọnu koto lọ. Niṣẹ ni awọn ọmọ pẹlu awọn iyawo bara jẹ ti wọn si n sunkun pe ẹni rere ti lọ. Bẹẹ lawọn mọlẹbi paapaa n bomi loju, ti awọn agba atawọn ọrẹ rẹ ti wọn fẹẹ ṣọkan ọkunrin, paapaa awọn ojugba ọkunrin naa nidii iṣẹ tiata n mi amikanlẹ lẹẹmẹẹwa, to si han loju wọn pe iku ẹni wọn naa dun wọn jọjọ.

Lati nnkan bii aago meje aabọ aarọ ọjọ keji ti ọkunrin naa ku, iyẹn ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ karun-un, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ni awọn mọlẹbi, ojulumọ atawọn ẹgbẹ baba yii nidii iṣẹ tiata ti n tu yaaya lọ sile rẹ to wa ni Wakajaye, niluu Ẹdẹ, nipinlẹ Ọṣun. 

Aago mẹrin irọle ni Alhaji Imaamu Jagunọganla ti ilu Ẹdẹ kirun si oku baba yii lara, lẹyin naa ni wọn gbe e wọ kaa ilẹ lọ.

Bii ala ni ọrọ iku Oloye Adedeji Aderẹmi, ẹni ti gbogbo eeyan mọ si Ọlọfa-ina, ṣi n jẹ fun pupọ awọn ọmọ orileede yii, paapaa, awọn eeyan ilu Ẹdẹ, nipinlẹ Ọṣun, nibi ti baba naa ti wa. 

Lati oṣu diẹ sẹyin la gbọ pe ojojo ti n ṣe ogun baba naa, ti ara ogun ko si le. Awọn ọmọ ti Ọlọrun fi ta baba naa lọrẹ ko wo o loju rara, niṣe ni wọn ṣugbaa rẹ lasiko ti aisan gbe baba naa dalẹ, Wọn kọkọ n tọju rẹ nileewosan aladaani kan niluu Ẹdẹ, nigba ti ko si ayipada to bi wọn ti fẹ ni wọn gbe e lọ UNIOSUN THC to wa niluu Oṣogbo. IbẸ naa ni wọn ti tun gbe baba yii lọ si Ọbafemi Awolọwọ University Teaching Hospital, niluu Ifẹ. 

Ṣugbọn aisan lo ṣee wo, ko sẹni to ri ti ọlọjọ ṣe. Ọsan ọjọ Tọsidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024, ni ọlọjọ de ba Baba Ọlọfa-ina, akukọ kọ lẹyin ọmọkunrin. Ọjọ yii naa ni wọn ti gbe oku rẹ wa sile gẹgẹ bi ọkan ninu awọn ọmọ baba naa, Adetunji Aderẹmi ṣe sọ fun akọroyin ALAROYE niluu Ẹdẹ, ko too di pe wọn bo o mọlẹ nirọlẹ ọjọ Ẹti.

Lara awọn agbagba oṣere ti wọn wa nibi isinku akẹgbẹ wọn yii ni Aderupọkọ, Abẹni Agbọn, Papalolo ati bẹẹ bẹẹ lọ. 

Ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Karun-un, ọdun 1950, ni wọn bi oṣere yii sinu idile Abdul Salam Aderẹmi, nigba ti orukọ iya rẹ n jẹ Aisha Aderẹmi, lati agboole Jagun Olukosi, niluu Ẹdẹ, nipinlẹ Ọṣun. O lọ sileewe alakọọbẹrẹ St Peters Anglican Primary School, laarin ọdun 1957 si ọdun 1962. Lẹyin iwe alakọọbẹrẹ rẹ lo tun tẹsiwaju lọ si Baptist Modern School, Ọdẹ-Omu, lọdun 1963 si 1965. Lẹyin eyi lawọn obi rẹ fi sẹnu ẹkọṣẹ, to si kọ iṣẹ kafinta ni akọyanju. Ẹnu iṣẹ naa lo wa to fi darapọ mọ awọn onitiata, labẹ ọga rẹ torukọ rẹ n jẹ Oyetunji. Latigba naa lo si ti n ṣe daadaa nidii iṣẹ to yan laayo yii.

Ọlọfana ti kopa ninu ere oriṣiiriṣii. Lara awọn ere to ti kopa ni ‘Ija Ọmọde’, eyi ti Korede Films gbe jade, ‘Idaamu Ọtunba’, lati ọwọ Adebayọ Salami, ‘Mayegun’ lati ọwọYinka Quadri ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Nitori akitiyan rẹ nipa gbigbe aṣa Yoruba larugẹ ati bo ṣe jẹ pe idagbasoke ilu Ẹdẹ to ti wa mumu laya rẹ ni wọn ṣe fi baba naa jẹ oye Ṣọbaloju Timi tilu Ẹdẹ.

Iyawo mẹrin ni Oloye Aderẹmi fẹ nigba aye rẹ, o si bi ọpọ ọmọ. 

 

Leave a Reply