Imaamu jade lọ ko wọle mọ, iwaju mọṣalasi lawọn agbebọn pa a si 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Imaamu mọṣalaṣi kan niluu New Jersey, lorileede Amẹrika, Hassan Sharif, ti jade aiwọle l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹta, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, niwaju mọṣalaṣi to duro si ni wọn ti yinbọn pa a.

Gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ, niwaju mọṣalaṣi kan to wa lagbegbe Newark, ni Iwọ-Oorun New York, lawọn agbebọn kan ti yinbọn fun oloogbe yii. Loootọ ni wọn gbiyanju lati ra ẹmi rẹ pada, ti wọn si sare  gbe e digba-digba lọ sileewosan, nibi to ti dagbere faye.

Agbẹjọru agba fun ilu New Jersey, Matt Platkin, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ṣọ pe iwaju mọṣalaṣi kan ni New Jersey, ni wọn ti yinbọn fun imaamu to doloogbe ọhun ko too di pe o pada ku sileewosan, o ni wọn yinbọn mọ Hassan laimọye igba lẹyin eyi ni wọn fi i sinu agbara ẹjẹ rẹ, ti wọn si ba tiwọn lọ.

Platkin ni, “A o ti i mọ ohun to ṣokunfa iwa ọdaran yii, ṣugbọn awọn ẹri ti a ti ri ko jọ fi han pe ki i ṣe nitori inunibini tabi

idunkoko mọ ni, bẹẹ ni ki ṣe pe wọn pa a nitori ọrọ ẹsin tabi tabi eyi to fara pẹ igbeṣumọmi. Pẹlu gbogbo rogbodiyan ati ainifẹ ara ẹni to n peleke si i lagbaaye, ọpọlọpọ awọn olugbe New Jersey, lo n gbe pẹlu inu fuu aya fuu”

O ni, awọn Musulumi to n gbe nipinlẹ naa lorilede Amẹrika n lọ bii ẹgbẹrun lọna ọọdunrun (3000,000), niye. Latigba ti ogun ti bẹrẹ laarin Isreal ati ikọ Hamas, ni awọn ẹlẹsin Islaamu ti n pọ si i ni tibu-tooro ilẹ Amẹrika.

Awọn alaṣẹ eto aabo lorilede Amẹrika (United States Transportation Security Administration (TSA), fidiẹ ẹ mulẹ pe Imaamu Sharif ti n ṣiṣẹ ni papakọ ofurufu ilẹ naa gẹgẹ bii ẹṣọ alaabo to n ṣe ayẹwo fawọn ero lati ọdun 2016.

Agbẹnuṣọ TSA, Lisa Farbstein, ni ibanujẹ nla ni iku oloogbe naa jẹ fawọn, tawọn si ti fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ si gbogbo awọn ọrẹ ati mọlẹbi rẹ.

Ẹgbẹ Musulumi kan lorilede Amẹrika, Council on American-Islamic Relations (CAIR), ẹka tipinlẹ New Jersey, juwe Sharif gẹgẹ bii adari rere. Wọn waa sọ pe ko siru iṣẹlẹ to le wu ko ṣẹlẹ, ṣiṣi ni awọn mọṣalaṣi yoo wa, awọn ko ni i ti i pa, ṣugbọn kawọn Musulumi gbogbo wa ni oju lalakan fi n ṣọri, paapaa ju lọ lawọn agbegbe ti wọn ti n gbogun ti Musulumi.

 

Leave a Reply