Eeeyan meji ku nibi ija Fulani ati Tapa ni Kwara

Ibrahim Alagunmu,  Ilọrin

Èèyàn méjì la gbọ́ pé wọ́n gba èkuru jẹ lọ́wọ́ ẹbọra níbi rògbòdìyàn tó wáyé llaarin ẹ̀yà Tápà tawọn eeyan tun mo si Nupe àti ẹ̀yà Fúlàní, tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì fara pa yánnayànna níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.

Ní nǹkan bii aago mẹ́sàn-án òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé, Mọnde, ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù karùn-ún, ọdún yii, ni gbọ́nmi sí i, omi ò tó o bẹ́ sílẹ̀ laarin àwọn ẹ̀yà méjèèjì ọ̀hún ní abúlé Padà, níjọba ìbílẹ̀ Edu, nípìnlẹ̀ Kwara.

ALAROYE gbọ pe èdè àìyedè náà bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn Fúlàní darandaran da maaluu wọ oko ìrẹsì wọn, tí wọ́n sì jẹ gbogbo rẹ̀ níjẹkújẹ.

Èyí ló fa a tí wọ́n fi fàáké kọ́rí, wọ́n fi jígà kọ́rùn, wọ́n bá ń pariwo pe awọn ko ni i gba.

Alága ẹgbẹ́ àwọn Fúlàní Gaa Allah, nípìnlẹ̀ Kwara, Ali Mohammed Jonwúrọ̀, dárúkọ ọ̀kan lára àwọn tó kú ọ̀hún bíi, Sanda Watanko, to sì sọ pé àwọn tó fara pa tí ń gba ìtọ́jú tó péye ní ilé-ìwòsàn báyìí.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọ̀kasanmi Àjàyí tó fìdi ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ niluu Ìlọrin, sọ pé lóòótọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkankan tó kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún. Gé̩gé̩ bó ṣe wí “ òòtọ̀ ni àwọn ẹ̀yà Nupe àti ẹ̀yà Fúlàní ń gbé nǹkan gbóná fún ara wọn, ṣùgbọ́n kò sí àkọsílẹ̀ pé ẹnikẹ́ni kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà “

Ọ̀kasanmi ni ohun gbogbo tí rodò lọọ mumi, kò sógun mọ́, kò sọ́tẹ̀ mọ́.

Leave a Reply