Princess, obinrin to fẹsun kan Baba Ijẹṣa, loun nile-ẹjọ yoo pada da lare

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Latari bawọn ọlọpaa ṣe faaye beeli silẹ fun Baba Ijẹṣa, Ọlanrewaju Omiyinka, lọjọ Aje ọsẹ yii, ti wọn ni ko maa lọ sile, obinrin to fẹsun kan an pe o ba ọmọ oun ṣerekere, iyẹn Princess torukọ rẹ gan-an n jẹ Damilọla Adekọya ti sọ pe bo ṣe le wu ki ẹjọ naa ri, oun ni kootu yoo pada da lare.

Oju opo ayelujara ni Princess kọ ọrọ kan si leyin itusilẹ Baba Ijẹṣa, ohun to kọ ree.’’Mo maa jare, ki i ṣe lẹsẹkẹsẹ, ṣugbọn ṣaka lo daju’’

O tun fi kun ọrọ rẹ naa pe, ‘‘Ọlọrun fẹran awọn ọmọde. Lodi si iṣekuṣe, lodi si  ifipabanilopọ, bi o ba si ri nnkan, sọ ohun to o ri.’’

Ko sohun to mu Princess jade sọrọ ju bawọn ọlọpaa ṣe yọnda Baba Ijẹṣa lọjọ Aje naa lọ, nitori ara ọkunrin naa ti wọn ni ko le to latimọle to ti wa fọjọ pipẹ ni wọn ṣe da a silẹ, lẹyin ti lọọya rẹ, Adeṣina Ogunlana, kede pe ara ọkunrin alawada naa ko ya latimọle, ipo ti ilera rẹ wa lewu.

Bi wọn ṣe yọnda Baba Ijẹṣa dun mọ ọpọ eeyan ninu, nitori wọn n sọ pe labẹ ofin, ko yẹ ki wọn ti i mọle pẹ to bẹẹ, nigba to jẹ ẹṣẹ to ṣẹ labẹ ofin ṣee gba beeli rẹ.

Bi wọn ṣe waa fi Ijẹṣa silẹ yii lo fa a tawọn eeyan fi n sọ pe nibo ni Iyabọ Ojo, ọrẹ ọlọrọ yoo foju si bayii, ti wọn n sọ pe kinni Princess to fi ọmọbinrin rọgbọdọ dẹ Baba Ijẹṣa naa yoo sọ.

Eyi ni Princess ṣe sọ tiẹ, Iyabọ paapaa si ti figba kan sọ pe oun ko mọ pe awọn ọmọ Naijriia ni ko fẹran otitọ, oun ro pe ijọba ni ko sunwọn tẹlẹ ni.

Gbara ti ọrọ yii ṣẹlẹ n’Iyabọ sọ eyi, nigba tawọn kan n pe fun gbigba beeli Ijẹṣa, ti Iyabọ si leri nigba naa pe iru ẹ ko ni i waye, to ni to ba kanran ki wọn fi Baba Ijẹṣa silẹ, oun yoo ta ile oun ṣẹjọ yii, ọrọ naa yoo si di intanaṣanna, yoo di ti agbaye ni.

Ṣugbọn ọpọ eeyan to da si ohun ti Princess sọ ni tiẹ ni wọn sọ pe ko si are kan ti yoo jẹ. Wọn ni to ba jẹ ọdun keje sẹyin to ni Ijẹṣa ba ọmọ oun sun lo ti sọrọ jade ni, ẹwọn n’Ijẹṣa ko ba ṣi wa titi dasiko yii.

Wọn ni ṣugbọn aisọrọ rẹ nigba naa ti ko ba a patapata, wọn ni afaimọ koun funra rẹ ma jẹjọ ni kootu bayii, nitori o fi ọmọge de ọkunrin ti ko mọ pe wọn n sọ oun, o si kẹ kamẹra si yara pe ko maa ya ohun ti wọn n ṣe.

Leave a Reply