Eeyan bii ọgọrun-un mẹta lo ti tun ni arun korona nilẹ wa bayii

Jide Alabi

Pẹlu bi nnkan ṣe n foju han, ko jọ pe arun korona ti i kuro nile wa tan patapata o! Eeyan bii ọọdunrun ni iwadii fi han pe o tun ni arun naa kaakiri ilẹ wa laipe yii gẹge bi ileesẹ to n mojuto itankale kokoro ati arun nilẹ wa ṣe gbe e jade lori ikanni abẹyẹwfo wọn lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, wọn ni eeyan bii ọgọrun-un mẹta lo ti tun lugbadi arun ọhun, eyi to mu iye eeyan to ti ko o nilẹ wa bayii le ni egbẹrun mẹrinlelọgọta.

Ipinlẹ mẹfa ni a gbọ pe awọn arun naa ti yọju bayii. Lara wọn ni ipinle Eko to ni ọtalenigba o din marun-un (255). Olu ilẹ wa l’Abuja lo tẹle e pẹlu bi awọn mẹtadinlọgbọ ti ṣe ni in, nigba ti awọn mẹwaa ṣẹṣẹ tun ni in lati ilu Ọyọ, awọn marun-un (5) lo ni i ni ni Kaduna, meji (2) ni Ondo ati ẹyọ kan niluu Kano.

Leave a Reply