Eeyan meje padanu ẹmi wọn nibi ti wọn ti n gba irẹsi tawọn kọsitọọmu n pin

Monisọla Saka

Latari bi ilu ṣe le koko, ti ebi si n pa araalu, eeyan meje ọtọọtọ lo ti ṣe bẹẹ gbẹmi-in mi lasiko ti wọn n ṣakitiyan lati ra irẹsi olowo pọọku nileeṣẹ aṣọbode ilẹ yii.

Gẹgẹ bi ikede to jade nileeṣẹ ajọ aṣọbode ilẹ wa, Nigerian Customs Service (NCS), ṣaaju akoko yii, pe gbogbo irẹsi tawọn gba lọwọ awọn to n ko o wọlu lọna aitọ, to fi mọ awọn ounjẹ mi-in lawọn fẹẹ ta fawọn araalu lowo pọọku, lojuna ati le din inira ti wọn n la kọja ku. Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Keji, ọdun yii, ni wọn bẹrẹ ounjẹ ọhun ni tita.

Irẹsi idaji apo, iyẹn 25kg, ni wọn n ta fawọn eeyan ni ẹgbẹrun mẹwaa Naira, nileeṣẹ wọn to wa lagbegbe Yaba, nipinlẹ Eko, niwọn igba tiru ẹni bẹẹ ba ti ni iwe iforukọsilẹ ọmọ Naijiria, National Identification Number (NIN).

Amọ o ṣe ni laaanu pe nibi tawọn eeyan kan ti n lakaka lati ri ra ninu ounjẹ olowo taṣẹrẹ ọhun ni wọn pari aye wọn si. Niṣe ni wọn tẹ wọn pa.

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọhun ni iroyin iku ọkunrin kan kọkọ gba ori ẹrọ ayelujara kan.

Bo tilẹ jẹ pe awọn tọrọ ṣoju wọn lori ila ti wọn to si, ti wọn si n tira wọn ni wọn kọkọ sọrọ iku ọkunrin tẹnikẹni ko mọ orukọ rẹ yii ọkunrin kan, Dr. Adunọla, ni ọsibitu oun ni wọn gbe ọkunrin naa digbadigba wa.

“O ni, ọkunrin kan ṣẹṣẹ ku sileewosan mi ni. Awọn eeyan tẹ ẹ mọlẹ lẹyin to ṣubu ni ọfiisi awọn kọsitọọmu to ti fẹẹ ra irẹsi. Oun pẹlu iyawo ẹ ni wọn wa lori ìlà ti wọn to si nigba to ṣadeede ṣubu, ṣugbọn ko tete ribi dide tawọn eeyan fi bẹrẹ si i gun un mọlẹ. O ba ni lọkan jẹ. Awọn ọmọ keekeeke ni oloogbe fi saye”.

Ẹni kan toun naa royin iku ẹlomi-in to waye nibẹ loju opo ayelujara sọ pe, awọn ero to wa nibẹ le ni ẹgbẹrun mẹwaa, nigba to di pe o n su wọn ni wọn fi agbara ya apa kan fẹnsi to yi ọfiisi awọn kọsitọọmu ka lulẹ, lojuna ati le ribi wọle kia.

Nitori ohun ti wọn ṣe yii, lilu ko to wiwọ ni awọn alaṣẹ ati ologun to wa nibẹ n fawọn eeyan ṣe, bẹẹ ni wọn tun n tẹ taju-taju (tear gas) si wọn lati tu wọn ka. O ni o ka oun lara pe awọn eeyan ko lanfaani lati ribi ṣe fidio nnkan to ṣẹlẹ, tori wọn yoo gba foonu ẹni yoowu ti wọn ba ka mọ pe o n ṣe fidio ni. O ni eyi to dun oun ju ni pe wọn lu obinrin kan to wa ninu kẹkẹ arọ, ki awọn eeyan too fagidi tuka nibẹ.

Bakan naa ni awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) agbegbe Yaba, nipinlẹ Eko, ti ọkan lara wọn, Arabinrin Comfort Funmilayọ Adebanjọ, padanu ẹmi rẹ sibi to ti fẹẹ ra irẹsi fi atẹjade sita.

Lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keji yii, ni alakooso FKL ward E1, ẹgbẹ oṣelu APC, Ọgbẹni Oluwafẹmi Fadahunsi, ati akọwe wọn, Comrade Adebari Adewale, fidi iku obinrin naa mulẹ. Ninu iwe ikede ipapoda rẹ ti wọn fi sita, wọn ni Oloogbe Adebanjọ jẹ ọkan lara awọn eeyan meje to ku lasiko ti wọlu-kọlu ṣẹlẹ lọọfiisi kọsitọọmu.

Wọn kọ ọ bayii pe, “Pẹlu ọkan to wuwo ati abamọ ni a fi kede ipapoda ọkan lara wa ni FKL Ward E1, Arabinrin Adebanjọ Comfort Funmilayọ, ti wọn n gbe ni Opopona Ibidun, Ojuẹlẹgba.

Ọkan lara awọn eeyan meje ti wọn ku lasiko ti wọn fẹẹ ra irẹsi kọsitọọmu ni Yaba ni wọn.

“Ki Ọlọrun rọ gbogbo mọlẹbi wọn, gbogbo awọn eeyan wọọdu E1, ni ọkan lati gba ofo ti ko ṣee rọpo pada yii”.

Ninu ọrọ ti Agbẹnusọ ajọ NCS, Abdullahi Maiwada, ba ileeṣẹ iroyin CNN sọ lo ti ni oun ko le sọ ni pato, bẹẹ loun ko le sọ pe irọ ni ọrọ pe awọn eeyan ku.

O ni gbara ti ọga agba ajọ naa l’Ekoo, Comptroller Adewale Adeniyi, ṣide irẹsi naa ni tita lọjọ Furaidee, lawọn eeyan ti n wa pẹlu erongba ati ri raisi ra, ṣugbọn nitori ọpọ ero to wa nibẹ, awọn eeyan ko ni suuru mọ, wọn bẹrẹ si i ti ara wọn to fi di oni rogbodiyan.

“Idarudapọ waye latari ainisuuru awọn eeyan lati tẹle ofin ti wọn la kalẹ fun tita irẹsi ọhun. Mi o le sọ pe bẹẹ ni tabi bẹẹ kọ ni awọn eeyan kan ku, ṣugbọn a ti n ṣewadii”.

Ko i ti i sẹni to le sọ boya eto irẹsi olowo pọọku tita yii yoo tun tẹsiwaju, nitori bo tilẹ jẹ pe ọrọ naa ti di ijọba ọrun afagbara wọ, ọpọlọpọ awọn eeyan ni wọn n sun iwaju ileeṣẹ kọsitọọmu mọju, nitori ki rira irẹsi naa baa le tete kan wọn.

Leave a Reply