Wọn ri ọmọ ọdun meji he l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọkunrin kan to n bọ lati iṣọ-oru laago marun-un kọja iṣẹju mẹwaa aarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keji, ọdun yii, ti ri ọmọdekunrin kan he.

Agbegbe Heavenly Gate, ni Owode-Ẹdẹ, nipinlẹ Ọṣun, la gbọ pe wọn ti ri ọmọ kekere naa.

Bi wọn ṣe ri i ni wọn gbe e lọ si mọṣalaaṣi apapọ ilu Ẹdẹ, lati kede. Bakan naa ni wọn tun gbe e lọ si aafin Olowode-Ẹdẹ, ṣugbọn wọn ko ri ẹnikankan yọju lati sọ pe oun mọ ọmọ naa.

Gẹgẹ bi agbẹnusọ ajọ sifu difẹnsi l’Ọṣun, Kehinde Adeleke, ṣe sọ, lẹyin ti gbogbo igbiyanju lati ri awọn obi ọmọ naa ja si pabo ni wọn gbe e lọ si ọfiisi ajọ sifu difẹnsi.

Adeleke sọ siwaju pe ọmọ naa ti wa ni agọ wọn to wa niluu Ido-Ọṣun, nipinlẹ Ọṣun, ki ẹni ti ọmọ rẹ ba sọnu lọ sibẹ pẹlu ẹri to daju.

 

Leave a Reply