Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọ Aiku, Sunnde, ọṣẹ yii, ni ibẹru-bojo gbilẹ, ti awọn eeyan si n sa kijokijo niluu Ijagbo, nigba ti ina ṣẹ yọ nileepo kan torukọ rẹ n jẹ TEM TEES, to wa niluu Ijagbo, nijọba ibilẹ Ọyun, nipinlẹ Kwara, ti eeyan meji, awakọ afẹfẹ gaasi ati ọkan lara swọn oṣiṣẹ ileepo naa si dero ile iwosan latari pe wọn fara pa nibi iṣẹlẹ naa.
Ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ ajọ panapana nipinlẹ Kwara, Hassan Hakeem Adekunle, fi sita lo ti ṣalaye pe ṣe ni ina ṣẹ yọ nile-epo naa lasiko ti ọkọ to n gbe afẹfẹ gaasi kan fẹẹ ja gaasi nileepo naa.
Awakọ afẹfẹ gaasi ati oṣiṣẹ ileepo ọhun fara pa yanna yanna, ileewosan kan niluu Ọffa ni wọn gbe awọn mejeeji lọ fun itọju to peye.
O tẹsiwaju pe ọpa afẹfẹ gaasi kan lo deede fọ ti ina fi ṣẹ yọ, eyi lo mu ki ibẹru-bojo gbilẹ ni agbegbe naa, ti awọn eeyan si n sa asala fun ẹmi wọn.
Adekunle ni ọpẹlọpẹ ajọ panapana to tete de sibi iṣẹlẹ naa ni ko jẹ ki nnkan bajẹ kọja afẹnusọ, tori pe wọn tete kapa ina ọhun. Adari agba ajọ naa, Ọgbẹni Falade Olumiyiwa, waa juwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii ohun to ba ni lọkan jẹ jọjọ, to si ni awọn to fara kaasa nibi iṣẹlẹ ọhun ti n gba itọju nileewosan kan niluu Ọffa.