Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Owo kan wa ti wọn maa n yọ lori ọja teeyan ba ra, to ba ko wọ ilu, tabi iṣẹ to ba ṣe, VAT lawọn oloyinbo n pe e, itumọ rẹ ni kikun si ni Value Added Tax.
Ijọba apapọ lo maa n gba owo yii lẹka Federal Inland Revenue Service (FIRS),bo tilẹ jẹ pe awọn to n san an le ma fi bẹẹ mọ, nitori wọn yoo ti ṣi i mọ ojulowo owo ọja ni.
Idajọ ile-ẹjọ giga kan ni Porthacourt to waa waye loṣu kẹjọ, ọdun yii, pe kijọba apapọ ma gba owo yii mọ, awọn ipinlẹ ni ki wọn maa gba a lo fẹẹ mu wahala ati awuyewuye dani bayii laarin ijọba apapọ atawọn ipinlẹ Naijiria.
Adajọ Stephen Pam, lo gbe idajọ kalẹ lọjọ kẹwaa, oṣu kẹjọ, ọdun 2021,pe eyi tijọba apapọ gba ninu owo-ori ọja yii to gẹẹ. O ni awọn gomina ni ki wọn maa gba a nipinlẹ wọn, ki wọn si maa fun ijọba apapọ niye to ba tọ si wọn.
Ṣe tẹlẹ, bijọba apapọ ba gba owo yii, wọn yoo pin in si ọna mẹta ni. Ijọba apapọ yoo yọ ida mẹẹẹdogun (15%), wọn yoo fun ijọba ipinlẹ ni ipin aadọta (50%), ijọba ibilẹ yoo si gba ida marundinlogoji (35%).
Ida marun-un ni ele owo-ori ọja yii tẹlẹ, (5%), ọjọ kin-in-ni, oṣu keje, ọdun 2020, ni wọn gbe ofin kan jade to sọ ọ di ida meje aabọ (7.5%) latigba naa lo si ti wa bẹẹ to jẹ ida meje aabọ yii lawọn eeyan n san.
Nibi ti wahala ti waa ṣẹlẹ ni pe ipinlẹ Eko ati Rivers ti ni ofin ile-ẹjọ to ni kawọn maa gba owo naa gẹgẹ bii ipinlẹ lawọn yoo maa tẹle bayii, wọn ni ijọba apapọ ko lẹtọọ lati tun maa gba a mọ.
Awọn ipinlẹ meji yii lowo lọwọ, wọn n gbe iṣẹ jade fawọn alagbaṣe, ero tun pọ nibẹ ti wọn n ṣiṣe aje, ti wọn si n pawo wọle funjọba ibẹ, iyẹn lawọn ṣe ni owo ilu awọn ko yẹ ko bọ sọdọ ijọba apapọ ju, ti wọn yoo maa waa yọ owo le awọn lọwọ. Wọn ni ohun to yẹ ni kawọn maa da owo ele ori ọja naa gba, kawọn si fun ijọba apapọ niye to ba tọ si wọn latọdọ awọn.
Nibi tawọn ipinlẹ meji yii ti n sọ eyi lawọn ipinlẹ bii Gombe, Katsina atawọn ilẹ Hausa mi-in ti ni awọn ko gba idajọ ile-ẹjọ yii wọle ni tawọn. Wọn ni bawọn ba ni kawọn maa gba owo-ori ọja yii funra awọn, ohun tawọn yoo pada na gẹgẹ bii ipinlẹ yoo ju ohun tijọba apapọ n fun awọn lọ.
Wọn ni bẹẹ si ree, owo tijọba apapọ n fun awọn lawọn fi n gbera. Awọn ipinlẹ mi-in ninu awọn ko le da owo-oṣu awọn oṣiṣẹ wọn san nilẹ Hausa yii bi ko ba jẹ pe ijọba apapọ fun wọn lowo ti wọn ti yatọ sọtọ fun wọn. Iyẹn lawọn ṣe ni awọn yoo pe ẹjọ ko-tẹmi-lọrun lori igbẹjọ to ni kijọba apapọ ma gba VAT mọ, wọn lawọn ko fara mọ ọn.
Awọn akọṣẹmọṣẹ nipa eto iṣuna naa ti figba kan da si ọrọ yii, wọn ni iṣẹ ijọba apapọ ni lati gba maa gba owo yii, ẹka to si n gba a naa ni Federal Inland Revenue Service (FIRS). Wọn ni awọn naa lo tọ si lati maa gba a lọ, nitori bi awọn ipinlẹ ba ni awọn yoo maa gba owo yii, atari ajanaku ni yoo jẹ fun wọn, ti ki i ṣe ẹru ọmọde. Wọn ni owo buruku ni yoo pada maa bọ lapo wọn sọdọ ijọba apapọ, eyi ti ko le pe wọn rara, yoo wulẹ bu wọn lọwọ ni.
Minisita eto iṣuna tẹlẹ, Kẹmi Adeọṣun, ti figba kan sọ ọ lọdun 2017, pe ipinlẹ Eko ni ida marundinlọgọta (55%) owo-ori ọja tijọba apapọ n san fawọn ipinlẹ ti n wa, ida marundinlogoji yooku, ọdọ awọn ipinlẹ marundinlogoji to ku ni Naijiria ni.
Eyi naa lo jẹ ki ọkan lara awọn akọṣẹmọṣẹ nipa kinni yii, Ọgbẹni Taiwo Oyedele, sọ pe awọn ipinlẹ yooku yii yoo padanu pupọ bi wọn ba n da gba owo yii, nitori owo ti yoo ti apo wọn jade yoo ju ohun ti yoo wọle sibẹ lọ. Afi Eko nikan to yatọ, to jẹ ko si ẹlẹgbẹ ẹ ninu awọn ipinlẹ Naijiria to ba di ti ọrọ aje.
Ṣugbọn awọn ipinlẹ to fẹẹ gbe igbesẹ gbigba owo yii funra wọn ti yari, wọn ni ko si kinni kan ti yoo yi ero awọn pada, ibi teeyan ba ti n ṣe naa lo ti gbọdọ jẹ.
Nyesom Wike, Gomina ipinlẹ Rivers, ti sọ ọ di aṣẹ nilẹ tiẹ, Eko naa, labẹ Gomina Babajide Sanwo-Olu, ti ni awọn ko ni i pẹẹ bẹrẹ si i gba owo-ori ọja yii funra awọn, bo ba jẹ kawọn kọwe sile-igbimọ aṣofin Eko ki wọn tete ṣe atunṣe sawọn ibi to yẹ labẹ ofin owo gbigba yii ni, kawọn si jẹ kawọn eeyan to ti n sanwo naa funjọba apapọ tẹlẹ ma ṣe bẹẹ mọ, ki wọn maa san an si asunwọn awọn, wọn lawọn yoo ṣe bẹẹ laipẹ rara.