Eeyan meji ku lojiji l’Abule-Ẹgba, mọto to n ko ọti kiri lo pa wọn

Aderohunmu Kazeem

Titi di asiko yii ni ileeṣẹ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri l’Ekoo ṣi n wa mọlẹbi awọn ọkunrin meji kan ti ẹmi wọn bọ nibi ijanba mọto to ṣẹlẹ lagbegbe Abule-Ẹgba, nipinlẹ Eko.

Mọto tirela nla kan to ko ọti lo nijanba pẹlu awọn mọto mẹta mi-in ni bọsitọọbu Al-Maruf, lagbegbe Abule-Ẹgba, eyi to mu awọn eeyan meji yii padanu ẹmi wọn lojuẹsẹ.

Olufẹmi Oke-Ọsanyintolu to jẹ ọga agba ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri sọ pe loootọ niṣẹlẹ ọhun waye, ati pe awọn ti gbe oku wọn lọ si mọṣuari. Bakan naa lo sọ pe lojuẹsẹ nileeṣẹ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri ti wa ojuutu si sun-kẹrẹ-fakẹrẹ, tiṣẹlẹ ọhun ko ba da silẹ.

Mọto akẹru to fa ijanba yii, igo ọti ni wọn sọ pe o kun inu ẹ bamu, ati pe lojiji ti ẹru ori ẹ rọ danu lo fa ijanba naa, ti mọto mẹta mi-in si faragba ninu iṣẹlẹ ọhun, ti ẹmi eeyan meji paapaa tun lọ si i.

Leave a Reply