Eeyan meji padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

O kere tan, eeyan meji lo padanu emi wọn nibi ijamba ọkọ to waye lopopona Ilọrin si Bode Saadu, nipinlẹ Kwara, lọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii.

Ilu kan ti wọn n pe ni Ọlọkọnla, loju ọna marosẹ Ilọrin si Bode Saadu, nipinlẹ Kwara, ni ijamba to mu ẹmi eeyan meji lọ naa ti waye.

Ninu atẹjade  kan ti Adari ẹsọ alaabo oju popo, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Jonathan Ọwọade, fi sita lọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, niluu Ilọrin, lo ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, to si ni eeyan mẹfa ni wọn fara kasa nibi iṣẹlẹ naa nigba ti taya ọkọ akero kan pẹlu nọmba iforukọsilẹ BFU947XA, sadede fọ, ti dẹrẹba to wa ọkọ naa,  Ọgbẹni Tekno, ko si ri ọkọ naa dari mọ

Ọwọade tẹsiwaju pe awọn ọlọpaa lo ko awọn to fara pa lọ sileewosan kan ti wọn n pe ni Adua, ni agbegbe naa, ti wọn si ko awọn oku lọ si yara igbokuu-si nileewosan olukọni Fasiti Ilọrin, (UITH). O fi kun un pe ajọ naa ti n ṣe ilanilọyẹ fawọn awakọ pe ki wọn maa yẹ ọkọ wọn wo loore koore ki wọn too maa gbe si oju popo, ki wọn si yee ra taya aloku mọ.

Leave a Reply