Eeyan meji pere ni mo ti fibọn mi pa lọdun yii, mo fi n daabo bo ara mi -Jẹmbẹ

Florence Babaṣọla

Ọmọkunrin ẹni ọdun mọkanlelogun kan, Gbenga Tọpẹ, ti sọ pe oun ki i deede lo ibọn ilewọ tawọn ọlọpaa ba ninu ile oun, lasiko ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun torukọ wọn n jẹ “Aye” ba n yọ oun lẹnu loun ma a n lo o.

Lasiko ti Kọmiṣanna ọlọpaa l’Ọṣun, Wale Ọlọkọde, n ṣafihan Tọpẹ, ẹni ti inagijẹ rẹ n jẹ Jẹmbẹ, lọmọkunrin naa ṣalaye pe ẹgbẹ okunkun “Ẹyẹ” loun wa, o ni ṣe loun n lo ibọn naa lati daabo bo ara oun.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, “Orukọ mi ni Gbenga Tọpẹ ti gbogbo eeyan mọ si Jẹmbẹ, ọmọ bibi ilu Ileṣa ni mi. Lasiko ti awọn ọlọpaa wa sile mi ni wọn ba ibọn kan nibẹ. Ọmọ ẹgbẹ okunkun ‘’Ẹyẹ’’ ni mi. Ṣe ni mo maa n lo ibọn yẹn lati daabo bo ara mi.

“Mo ti figba kan lọ sọgba ẹwọn, nigba ti mo pada de lo di pe ki awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ‘’Aiye’’ n lepa mi kaakiri. Awọn ‘‘Aiye’’ yii ni wọn pa ẹgbọn mi, Jasper, lọdun 2017, wọn tun yinbọn mọ mi nigba ti mo de lati ọgba ẹwọn, idi niyẹn ti mo fi sa lọ sọdọ ẹni to mu mi wọnu ẹgbẹ Ẹyẹ, Forilamoney, pe ko gba mi.

“Forilamoney sọ fun mi pe oun n lọ s’Ekoo, ṣugbọn o ṣẹleri lati fun mi ni ibọn to ba pada de, bo ṣe de naa lo fun mi. Mo ti lo ibọn yẹn lati fi gbẹmi awọn ọmọ ‘Aiye’ meji ninu oṣu keji, ọdun yii, lagbegbe Asọjẹ, nibi ti Lekan Emir n gbe, ṣugbọn n ko ranti orukọ wọn ati ọjọ ti mo pa wọn.

“Igbo [indian hemp] ni mo maa n ba Forilamoney ta, ija kan to si ṣẹlẹ laarin oun ati ẹnikan to n jẹ Ori-agbo toun naa n ta igbo lagbegbe Ọbatẹdo, niluu Oṣogbo, lo gbe mi de ọgba ẹwọn ti mo lọ ki n to pada wale.”

“Ti mo ba ti fi ibọn mi ṣiṣẹ tan, ṣe ni mo maa n fi i pamọ, ibi ti mo si maa n tọju rẹ si lawọn ọlọpaa ti ri i.”

Ni bayii, Ọlọkọde ti ṣeleri pe ni kete ti iwadii ba ti pari ni Tọpẹ yoo foju bale-ẹjọ.

Lẹyin bii ọsẹ meji ti wọn ti n wa a, wọn ba oku Jọkẹ nihooho ninu igbo labule Atoyọ.

Leave a Reply