Eeyan mẹjọ padanu ẹmi wọn nibi ija awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun

Monisọla Saka
Ko din ni eniyan mẹjọ ti wọn ti dẹni ana nibi ikọlu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun lawọn agbegbe kan niluu Benin, nipinlẹ Edo.
Bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to ti i mọ awọn ti wọn ṣiṣẹ ibi ọhun, sibẹ, iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe, ọmọkunrin kan to fi ẹgbẹ okunkun tiẹ silẹ lọọ darapọ mọ ẹgbẹ mi-in, eyi ti awọn ẹgbẹ to wa tẹlẹ ka si eewọ lo da wahala naa silẹ.
Ni gẹrẹ to kuro ninu ẹgbẹ to wa tẹlẹ lawọn ọmọ ẹgbẹ ọhun lọọ binu pa a, eyi lo si mu ki awọn ẹgbẹ tuntun to ṣẹṣẹ dara pọ mọ yari pe afi kawọn gbẹsan iku ẹ ni.
Ohun ti iroyin sọ ni pe ọkan ninu awọn ikọ ọmọ ẹgbẹ okunkun naa wa ọkan lara awọn ti wọn n dọdẹ lọ si agbegbe Wire Road, ṣugbọn ti wọn pa iya ẹ gẹgẹ bii aroko kalẹ fun un nigba ti wọn o ri ọmọ ti wọn n wa.
Agbegbe Asoro, Igbukguoko, Evbuotubu lati agbegbe Ogida, titi de Wire road, Ibiwe ati Ebo ni awọn kolọransi ọmọ naa ti ṣọṣẹ, ti wọn si ti paayan.

Amọ ṣa o, ọga ọlọpaa ipinlẹ Edo ni eeyan meji ọtọọtọ ni wọn yinbọn pa nigboro Benin l’Ọjọru, Wẹsidee.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Chidi Nwabuzor ṣalaye l’Ọjọbọ, Tọsidee, pe, “Emi o mọ nipa eeyan mẹjọ ti wọn pa o. Ohun ti mo mọ ni pe, l’Ọjọruu, Wẹsidee, wọn ṣe ikọlu, wọn si pa ọkunrin kan lagbegbe Ugbowo, mo si pe awọn agbofinro lati wa nnkan ṣe si i. Lọgan ni ọga ọlọpaa agbegbe ibẹ si ti de ibi iṣẹlẹ ọhun, ti wọn si palẹ oku naa mọ kuro nibẹ.
“Bakan naa, lọsan-an ọjọ yii kan naa, wọn pe wa lati ileeṣẹ ijọba, Pubilc Work Volunteer pe, awọn afurasi kan sadeede gbe mọto wa, wọn si yinbọn pa oṣiṣẹ kan lasiko to wa lẹnu iṣẹ.

Leave a Reply