Stephen Ajagbe, Ilorin
Eeyan mẹsan-an lo jona kọja idamọ nibi ijamba ọkọ to gbẹmi-in awọn mẹwaa lọjọ Keresimesi loju ọna Idọfian si Ilọrin, nipinlẹ Kwara.
Ijamba ọhun ṣẹlẹ nitosi ẹka ileewe Unilorin Sugar Research Institute to wa ni titi morosẹ naa, lasiko ti mọto meji; Nissan Vanette ati Honda Accord, ti eeyan mẹtadinlọgbọn wa ninu ẹ kọ lu ara wọn.
Ọga agba ajọ to n mojuto igboke-gbodo ọkọ loju popo, FRSC, ẹka tipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Jonathan Ọwọade, to fidi rẹ mulẹ ṣalaye pe ere asapajude ati wiwa ọkọ lai bikita lo fa ijamba naa.
O ni awọn mẹrindinlogun lo fara pa, ti wọn si wa nileewosan ẹkọṣẹ Fasiti Ilọrin, UITH ati ilewosan jẹnẹra, nibi ti wọn ti n gba itọju. O fi kun un pe diẹ lara wọn wa nilewosan Ilẹ Anu, niluu Idọfian.
Ọwọade ni eeyan kan pere lara awọn ero inu ọkọ naa ni ko fara pa. Ilewosan UITH lo ni awọn ko oku awọn to padanu ẹmi wọn si.
O gba awọn awakọ nimọran lati maa ṣe suuru loju titi, ki wọn si din ere sisa ku.