Lẹyin ọdun mẹtala to ti jona, wọn tun aafin Ọwa Obokun kọ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

 

Beeyan ba gun ẹṣin ninu Ọwa Obokun ti ilẹ Ijeṣa, Ọba (Dr) Gabriel Adekunle Aromọlaran 11, CFR, lonii, onitọhun ko ni i kọṣẹ. Odidi ọdun mẹta ni baba naa ko fi sun aafin, ṣugbọn ni bayii, inu aafin ni wọn aa maa gbe.

 

Ohun to fa sababi ni pe inu oṣu keje, ọdun 2007, ni ina ọmọ-ọrara deede sẹ yọ ninu aafin naa, to si jo o gburugburu. Latigba naa ni Ọba Adekunle ti n gbe ninu ile rẹ to wa loju-ọna Ileṣa/Ijẹbu Jeṣa.

 

Gbogbo igbiyanju awọn ọmọ ilu naa lati tun aafin naa kọ ni ko so eso rere, afigba ti wọn gbe igbimọ kan kalẹ loṣu mẹsan-an sẹyin labẹ alaga Oloye Yinka Faṣuyi.

 

Igbimọ naa bẹrẹ iṣẹ takuntakun lori atunkọ aafin naa, wọn kan si awọn ọmọ ilu yii kaakiri agbaye, wọn si ko owo jọ lori rẹ.

 

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, owo ti wọn fi tun aafin naa kọ to miliọnu lọna ọọdunrun un naira, ọjọ Abamẹta, Satide, ni wọn yoo ṣi aafin naa, ti wọn yoo si ko kọkọrọ le Ọwa Aromọlaran lọwọ.

Leave a Reply