Eeyan mẹta jona ku ninu ijamba ọkọ ni marosẹ Eko s’Ibadan

Yatọ si bi mọto to ba n sare asapajude ṣe maa n gbokiti, ti awọn eeyan yoo padanu ẹmi loju popo, niṣe ni mọto akẹru kan ti ko ni nọmba, ṣugbọn to n sare buruku lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ ta a lo tan yii, loju ọna marosẹ Eko s’Ibadan gbina ni tiẹ, eeyan mẹta si jona ku gburugburu loju-ẹsẹ.

Agbegbe ileepo Danco ni ijamba naa ti waye ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ ku diẹ. Alaye ti Kọmanda Ahmed Umar to jẹ ọga awọn FRSC nipinlẹ Ogun si ṣe ni pe niṣe ni ọkọ akẹru naa n sare ju loju ọna yii, ere naa pọ debii pe o padanu ijanu ẹ, apa awakọ yii ko ka mọto naa mọ, to bẹẹ to jẹ niṣe lo lọọ kọlu tirela kan to n lọ niwaju ẹ.

Ṣugbọn bii igba ti ẹyin fori sọ apata ni. Umar sọ pe niṣe ni mọto akero naa gbina lojiji, ti mẹta ninu awọn ọkunrin marun-un to wa nibẹ si jona gburugburu, bẹẹ lẹni kẹrin naa fara kona, bo tilẹ jẹ pe oun ko ku, ọsibitu Ìdèra, ni Ṣagamu, ni wọn gbe e lọ, mọṣuari ibẹ ni wọn ko awọn oku meta naa lọ pelu.

Gẹgẹ bi iṣe wọn, ajọ FRSC tun rọ awọn awakọ pe ki wọn yee fi ere sisa ba ohun to dara jẹ? Ki wọn yee fẹmi alaiṣẹ tafala, ki wọn yee fi iṣẹ ọwọ wọn sọ ọpọ ile dahoro nitori iwakuwa wọn

 

Leave a Reply