Eeyan mẹta tun jona ku ninu ijamba ọkọ l’Akungba Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Eeyan mẹta ni wọn jona ku, tawọn mi-in si tun ṣeṣe ninu ijamba ọkọ to waye l’Akungba-Akoko loru ọjọ Isẹgun, Tusidee, mọju Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu ọkunrin kan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ pe ohun to ṣokunfa ijamba ọhun ko sẹyin bi awọn ọkọ akẹru J5 meji ṣe fori sọra wọn ni nnkan bii aago meji oru ọjọ naa, leyii to mu ki ina nla sọ lojiji lara awọn ọkọ mejeeji.

O ni awọn eeyan ti ko tete jade si wọn lati ran wọn lọwọ lasiko ti iṣẹlẹ ọhun waye wa lara idi tawọn ero kan fi jona gburugburu mọ inu ọkọ ọhun, ti awọn mi-in si tun fara pa nigba ti awọn diẹ raaye rapala jade

Lẹyin-o-rẹyin lo ni awọn ọlọpaa pada de si ibi tí ijamba naa ti sẹlẹ, tí wọn si ṣeto bi wọn ṣe ko awọn to fara pa lọ sile-iwosan.

Leave a Reply