EFCC gba mọto mejidinlogun lọwọ awọn ọmọ  ‘Yahoo’ ti wọn mu l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 Ko din ni eeyan mẹtalelọgbọn (33) ti wọn ko niṣẹ meji ju Yahoo ṣiṣẹ lọ, ti ọwọ ajọ EFCC to n ri si ẹsun jibiti, ba l’Abẹokuta bayii. Mọto ayọkẹlẹ mejidinlogun si wa lara ẹru ofin ti wọn ri gba lọwọ wọn.

Ọjọbọ, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹrin yii, ni aṣiri awọn tọwọ ba naa tu, nigba ti Agbẹnusọ EFCC, Wilson Uwujaren, fi atẹjade sita pẹlu orukọ awọn eeyan naa ati fọto wọn.

Awọn ti wọn mu naa ni: Sọdiq Kotoyẹ, Lawal Sọfiu, Abiọla Gabriel, Olufowobi Adeniyi, Lateef Taiwo, Oyebasi Damilọla, Oluwatoyin Awonuga, Akinbọde Azeez, Kayọde Victor, Sulaimọn Abdullahi, Adekọna Tọlani, Babatunde Rotimi, Oduwọle Ọlatokunbọ, Fatai Habeeb, Fashọla Pẹlumi, Obitokun Olugbade, Atẹwọjaye Oluwadamilare, Fawaz Calfos,Ọbadina Tobi, Eugushi Mumuni, Ehis Hopkins, Kọlawọle Bankọle ati Balogun Tọheeb.

Awọn yooku ni: Alaka Ismail, Adebọwale Babatunde, Yusuf Ajibọla, Adeoye Hammed, Ọmọlayọ Odutọla, Musbaudeen Azeez, Anifowoshe Bamidele, Habeeb Ibrahim, Ọladimeji Ọdunayọ ati Ọpatọla Malik Sunday.

Awọn adugbo bii Adigbẹ, Oloke, Ibara Housing ati Idi-Ori, l’Abẹokuta ni wọn ti mu awọn onijibiti ori ayelujara naa.

Agbẹnusọ EFCC sọ pe olobo lo ta awọn lori iwa tawọn ọmọ naa n hu, eyi ti i ṣe iwa ọdaran to lodi sofin.

Yatọ si mọto ayọkẹlẹ mejidinlogun ti wọn ri gba lọwọ wọn, awọn foonu oriṣiiriṣii, kọmputa agbeletan atawọn iwe ti wọn fi n lu jibiti ọlọkan-o-jọkan ni wọn tun ba lọwọ wọn bi Uwujaren ṣe sọ.

Bi kootu ba ti bẹrẹ iṣẹ pada, awọn afurasi naa yoo balẹ sibẹ gẹgẹ bi ajọ EFCC ṣe wi.

Leave a Reply