EFCC mu Awiṣẹ, babalawo ti wọn lo lu jibiti miliọnu igba ataabọ naira l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ọwọ ajọ EFCC to n ri si ẹsun jibiti ti ba gbajumọ babalawo kan bayii ti wọn n pe ni Awiṣẹ, niluu Abẹokuta, ẹni ti orukọ rẹ gan-an n jẹ Abayọmi Kamaldeen Alaka. Wọn lo gba milọnu lọna igba ataabọ naira (250m) lọwọ onibaara rẹ kan, iyẹn ko si ri iwosan to tori ẹ kowo silẹ.

Olori ẹka iroyin awọn EFCC, Ọgbẹni Wilson Uwujaren, to fi iṣẹlẹ naa sita pẹlu fọto Awiṣẹ, ṣalaye pe obinrin kan, Bright Juliet, ni ọkunrin ti ojubọ rẹ wa l’Abule Aṣipa, l’Abẹokuta, naa lu ni jibiti owo nla yii.

O fi kun un pe aarẹ kan lo n ṣe Bright Juliet, to nawo si i titi ti kinni naa ko lọ. O ni nibi to ti n wa iwosan kiri lo ti pade obinrin kan tiyẹn n jẹ Akinọla Bukọla Augustina (Iya Ọṣun), lori ẹka ayelujara Fesibuuku.

Iya Ọṣun yii lo ti kọkọ gba owo to to miliọnu mẹrindinlogun naira (16m) lọwọ obinrin to n wa iwosan yii, to loun yoo tọju rẹ, ṣugbọn oun naa gbowo titi ni, ko ri kinni ọhun wo san. Nigba to si ti yo tan ni tiẹ lo taari alaisan naa sọdọ Awiṣẹ, o ni yoo ba a wo ohun to n ṣe e naa san lai ṣiyemeji.

Bayii lo ṣe di pe Bright Juliet bẹrẹ si i lọ sọdọ Awiṣẹ. Gẹgẹ bi olori ẹka iroyin EFCC yii si ṣe wi, o ni obinrin naa ṣalaye fawọn pe oju lasan kọ ni Awiṣẹ fi bẹrẹ si i gbowo lọwọ oun, o jọ pe taṣẹ-taṣẹ ni.

Awọn owo to san lati inu akanti tiẹ si ti ọkunrin babalawo yii, ateyi to jẹ niṣe lo fọwọ ara ẹ ko o lọ kiṣi, pẹlu eyi to san si akanti Mọla kan to n ṣẹwọ ilẹ okeere, ẹni ti wọn pe orukọ ẹ ni Sani Mohammed, gbogbo ẹ ni obinrin naa sọ pe ẹri wa fun.

Bẹẹ, bo ti n sanwo naa to, ko ri iwosan kan, wọn kan n lu u ni jibiti titi towo naa fi pe igba ati idaji miliọnu naira ni .

Lọjọ ti oṣunwọn irẹnijẹ naa kun ni Bright kọwe ifisun si EFCC lori awọn to gba a yii, awọn si bẹrẹ si i dọdẹ wọn kiri titi tọwọ fi ba wọn nikọọkan.

Lọjọ kọkanlelogun, oṣu karun-un, ọdun 2021, lọwọ wọn ba Sani Mohammed ati Akinọla Bukọla Augustina ( Iya Ọṣun). Ẹgbẹda ni wọn ti mu Sani, wọn mu Iya Ọṣun ni Abule-Ẹgba, l’Ekoo kan naa.

Iya Ọṣun lo mu awọn EFCC lọ si Aṣipa ti wọn ti mu Awiṣẹ, ṣugbọn ọkunrin naa ti gbọ pe wọn n bọ, n lo ba na papa bora, wọn o ri i mu lọjọ naa, ki wọn too waa ri i mu bayii.

Bi wọn ṣe mu Awiṣẹ yii lawọn EFCC bẹrẹ si i tudii ẹ wo, wọnyi lawọn ohun ti wọn sọ pe o ti ko jọ ninu iṣẹ gbaju-ẹ to n ṣe.

Ilẹ rẹpẹtẹ l’Aṣipa, Abẹokuta, nibi ti wọn ti n tan awọn eeyan jẹ, ti wọn si fi ṣe ojubọ wọn.

Ile-epo tuntun kan ti wọn n pe ni Alaka Oil and Gas, to wa l’Ojule keji, Opopona Adenẹyẹ,Oke-Oriya, Ikorodu. Gbọngan ayẹyẹ kan to n kọ lọwọ, eyi ti wọn pe ni Alaka Event Centre, toun naa wa l’Ojule keji, Opopona Adenẹyẹ, Oke–Oriya, Ikorodu.

Ile fulati rẹpẹtẹ kan tun wa nibi ti gbọngan ayẹyẹ wa yii naa, ati ile alaja kan to ni bọiskọta, toun wa l’Ojule kejilelogun, Opopna PSSDC, Magodo Phase 2, l’Ekoo.

Ṣaa, wọn ti ni Awiṣẹ yoo foju kan kootu laipẹ, nigba ti iwadii ba pari

Leave a Reply