EFCC ti mu minisita Buhari, biliọnu rẹpẹtẹ ni wọn lo ko jẹ

Monisọla Saka

Ajọ to n gbogun ti ajẹbanu ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku lorilẹ-ede wa,  Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ti nawọ gan Hadi Sirika, ti i ṣe minisita feto irinna oju ofurufu labẹ iṣejọba Aarẹ Muhammadu Buhari, nitori owo to le diẹ ni biliọnu mẹjọ Naira to poora labẹ rẹ.

Ni nnkan bii aago kan ọsan ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni ọkunrin yii de si ọfiisi EFCC to wa lagbegbe Wuse, niluu Abuja.

Lara awọn ẹjọ to ni lati jẹ ni ayederu iṣẹ akanṣe kan to gbe fun ileeṣẹ Engirios Nigeria Limited, ileeṣẹ ti wọn ni aburo Hadi, iyẹn Abubakar Sirika, lo ni in.

Oun pẹlu aburo rẹ yii ni wọn fẹsun kan pe wọn jọ lẹdi apo pọ lati kowo naa jẹ.

Ilẹdi apo pọ lati ja ilu lole, lilo ọfiisi rẹ nilokulo ati dida owo ilu sapo ara ẹ ni awọn ẹsun ti wọn fi kan minisita atijọ naa. Ẹẹmẹrin ọtọọtọ ni wọn ni Hadi gbe iṣẹ akanṣe fun awọn ileeṣẹ kan, eyi ti Engirios Nigeria Limited, to jẹ ti aburo rẹ yii jẹ ọkan lara ẹ. Apapọ owo to jade latari iṣẹ to loun n gbe sita yii le ni biliọnu mẹjọ Naira, amọ ti wọn ko ri iṣẹ kankan ko tibẹ jade.

Awọn iṣẹ akanṣe ti tẹgbọn-taburo yii fi ja ilu lole, ni wọn fi wọ odidi biliọnu mẹjọ Naira laarin ọdun 2022 si 2023.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ EFCC to n wadii ẹsun ikowojẹ yii ni, “Abubakar ti i ṣe aburo rẹ ni Hadi gbe iṣẹ yẹn fun, pẹlu bo ṣe mọ pe oṣiṣẹ ijọba to di ipo igbakeji adari mu nileeṣẹ ijọba apapọ to n mojuto ọrọ omi lo wa.

“Lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022, ni wọn kọkọ san owo to le ni biliọnu kan Naira (1.3 billion), sinu akanti ọkunrin yii, lati fi kọ aaye ibi tawọn arinrin-ajo ti maa n wa ki wọn too wọ baaluu ti wọn n pe ni Terminal sinu papakọ ofurufu ipinlẹ Katsina. Ẹlẹẹkeji to waye lọjọ kẹta, oṣu Kọkanla, ọdun 2022 kan naa, ni wọn ni awọn fẹẹ fi ṣeto didena ina ninu papakọ ofurufu Katsina, owo to din diẹ ni biliọnu mẹrin Naira (3.8 billion), ni wọn lawọn na lori eyi.

“Ẹkẹta to waye lọjọ kẹta, oṣu Keji, ọdun 2023, jẹ ẹgbẹta miliọnu Naira o le, ẹrọ to maa n gbe ni lọ soke sisalẹ nile oloke ti won n pe ni ‘lift’, ẹrọ amuletutu ati ile jẹnẹretọ fun papakọ ofurufu ilu Abuja, ni wọn ni ki ileeṣẹ naa ko wa. Nigba ti owo ẹlẹẹkẹrin ti wọn san wọle sinu akanti Abubakar waye lọjọ karun-un, oṣu Karun-un, ọdun 2023, fawọn oohun eelo kan sinu ileewe ẹkọṣẹ eto irinna oju ofurufu ipinlẹ Kaduna, Nigerian College of Aviation Technology, Zaria. Owo to le ni biliọnu meji ni wọn san fun eyi.

“Ninu gbogbo owo to le ni biliọnu mẹjọ ti wọn fi sanwo iṣẹ akanṣe yii, biliọnu mẹta o le (3.2 billion), ni minisita ana yii san sinu banki ileeṣẹ aburo rẹ. Ni kete to denu akanti rẹ loun naa fi ṣọwọ si oriṣiiriṣii ileeṣẹ atawọn eeyan. Bẹẹ ni a ko ri i ki wọn ṣiṣẹ kankan lorukọ owo ti wọn san yii titi di oni”.

O ṣalaye siwaju si i pe lati ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ Kẹrin, oṣu Keji, ti wọn ti nawọ gan Abubakar Sirika, akolo awọn lo ṣi wa, ni olu ileeṣẹ EFCC, nibi to ti n ran awọn lọwọ lori iwadii nipa bi owo ṣe rin nileeṣẹ eto irinna ọkọ ofurufu lasiko ti ẹgbọn rẹ, Hadi Sirika, jẹ minisita nibẹ.

Leave a Reply