Iyawo mi n yan ale, ko tun fi mi lọkan balẹ, mo fẹẹ kọ ọ-Shuaibu 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Lẹyin ti baale ile kan, Shuaibu Ọba, tu gbogbo aṣiri iwa buruku ọwọ iyawo ẹ, Afusat Garuba, niwaju ọkẹ aimọye eeyan ni kootu ibilẹ kan to wa laduugbo Akérébíata, niluu Ilọrin, nitori ki adajọ le fopin si ajọṣepọ to wa laarin awọn mejeeji, adajọ ti sun igbẹjọ wọn siwaju.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, lọkunrin naa ṣalaye pe niṣe loun maa n fẹẹ le tọ sara ni gbogbo igba ti oun ba ti fi oju kan iyawo oun. Idi ni pe ki i fi oun lọkan balẹ rara, bakan naa lo tun n ṣagbere.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, “Ohun ni mo fẹ gẹgẹ bii iyawo keji, to si bimọ kan fun mi, ṣugbọn ọrọ rẹ ti su mi bayii, ti mo si fẹ ka pin gari.

Shuaibu to peyawo ẹ lẹjọ yii fi kun un pe obinrin naa n ṣagbere mọ oun lara.

O waa rọ ile-ẹjọ lati fopin si igbeyawo to wa laarin oun ati olujẹjọ

Ninu ọrọ olujẹjọ, Afusat, o sọ fun ile-ẹjọ pe oun ko ṣetan lati kọ ọkọ oun, ati pe sadeede ni olupẹjọ mu iwe kootu wa pe kawọn pin gari, “gbogbo ohun ti ọkọ mi sọ nipa mi ki i ṣe ootọ”

Adajọ Yunusa Abdullahi ti waa fun awọn tọkọ-taya naa ni anfaani ọṣẹ meji ki wọn lọọ yanju rẹ laarin mọlẹbi, ṣugbọn ti wọn ko ba ri ọrọ naa yanju, ki wọn pada wa. Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹjọ, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii.

Ọmọ ti ko ba pe ọdun mejidinlogun ko gbọdọ wọ ileewe giga fasiti mọ

Eyi ni ọdun tọmọ gbọdọ pe ko too wọle iwe giga

 

Leave a Reply