EFCC foju gomina Kwara tẹlẹ, Abdulfatai Ahmed, bale-ẹjọ  

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, ni ajọ to n gbogun iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), yoo foju gomina ipinlẹ Kwara tẹlẹ, Abdulfatai Ahmed, ba ile-ẹjọ giga ipinlẹ naa to fikalẹ siluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, lori awọn ẹsun ikowojẹ ti wọn fi kan an.

Bi gomina tẹlẹ ọhun ṣe de ọfiisi wọn ni wọn ko jẹ ko sile lọjọ naa, ti wọn si ju u sahaamọ wọn.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Keji yii, ni awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP, ẹka tipinlẹ Kwara, ṣe fẹhonu han lọ sileeṣẹ EFCC. Wọn ni ko ba ofin mu bi wọn ṣe ti Abdulfatai Ahmed, ṣahaamọ, ti wọn si n pe fun ki ajọ tu u silẹ ni kiakia.

Bakan naa ni wọn tun fẹsun ijọba Kwara, pe nitori ti olujẹjọ yii ko darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC, ni wọn ṣe wahala rẹ.

Ni bayii, ajọ naa ti ni lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Keji yii, ni afurasi naa yoo kawọ-pọnyin rojọ nile-ẹjọ giga kan to fi ilu Ilọrin ṣe ibujokoo.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keji yii, ni ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku (EFCC), ẹka tilu Ilọrin, ti ranṣẹ pe Abdulfatai Ahmed, lori ẹsun biliọnu mẹsan-an Naira ti wọn ni o poora lasiko iṣẹjọba rẹ laarin ọdun 2011 si ọdun 2019.

 

Leave a Reply