Eyi lohun tileewe Fasiti KWASU sọ nipa akẹkọọ wọn to dawati

 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Awọn alaṣẹ Fasiti tipinlẹ Kwara (KWASU), Màlété, ti ni ọmọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelogun nni, AbdulMueez Jimọh Ọlamilekan, ti iroyin rẹ jade pe o dawati ki i ṣe akẹkọọ awọn mọ, wọn ni lati ọdun 2021 ti ko ti ri owo ileewe san lo ti kuro ni akẹkọọ awọn.

Ṣugbọn ninu atẹjade kan ti awọn alaṣẹ ileewe naa gbe jade l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Keji yii, latọwọ Alukoro wọn, Dokita Saeedat Aliyu, lo ti ni iroyin ti wọn n gbe kiri pe akẹkọọ Fasiti KWASU ni AbdulMueez Jimọh, to dawati, jẹ irọ to jinna sootọ ni.

O tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe ninu akọsilẹ ileewe ọhun, o han pe AbdulMueez Jimọh, ki i ṣe akẹkọọ awọn latari pe lati ọdun 2021-2022, ni ọmọkunrin naa ko ti ri owo ileewe san, eyi to ṣokunfa bo ṣe padanu ẹtọ rẹ gẹgẹ bii akẹkọọ Fasiti KWASU. Fun idi eyi AbdulMueez Ọlamilekan Jimoh ki i ṣe akẹkọọ KWASU, bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa ti n ṣiṣẹ takuntakun lati wa ọmọkunrin naa lawaari.

Tẹ o ba gbagbe, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Keji yii, ni iroyin gba gbogbo ori ayelujara pe akẹkọọ Fasiti KWASU kan, AbdulMueez Jimoh, to jẹ akẹkọọ lẹka imọ Kọmputa nileewe ọhun dawati lẹyin to dagbere fun awọn ọrẹ ẹ ni Màlété, pe oun lọ siluu Ilọrin, lọdọ awọn obi oun.

Leave a Reply