Wọn ti mu awọn eleyii, aṣọ ṣọja ni wọn fi n lu jibiti l’Ekoo

Adewale Adeoye

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ni awọn gende meji kan,  Jonathan Yahaya ati  Mohammed Umar, ayederu ṣoja ti ọwọ tẹ wa.

ALAROYE gbọ pe o ti pẹ tawọn ayederu ṣọja ọhun ti n lọ kaakiri ipinlẹ Eko, ti wọn si n faṣọ ijọba ṣe gbaju-ẹ fawọn araalu, ko too di pe ọwọ tẹ wọn laipẹ yii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wesidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Keji, ọdun 2024 yii, sọ pe ọgagun kan ti ko darukọ ara rẹ to wa pẹlu ẹka ileeṣẹ ologun orileede yii ‘81 Division’, ni Bonny Camp, Victoria Island, niluu Eko, lo ri awọn ọdaran ọhun lasiko ti wọn n lọ, ẹni akọkọ wọ ṣokoto ṣọja ati bata, nigba ti eni keji wọ aṣọ ṣọja ati fila. O da awọn mejeeji duro, o beere awọn ibeere kan lọwọ wọn, ṣugbọn wọn ko ri esi gidi kan fi si i. Lo ba fọwọ ofin gba wọn mu loju-ẹsẹ. Teṣan ọlọpaa agbegbe Onikan, lo mu wọn lọ pe ki awọn ọlọpaa ba wọn ṣẹjọ lori iwa radarada ti wọn hu.

Alukoro ni awọn maa too foju awọn oniṣẹ ibi ọhun bale-ẹjọ, ki wọn le jiya ẹṣẹ ohun ti wọn ṣe

Leave a Reply