Ọgbọn biliọnu Naira nijọba apapọ fawọn gomina lati yanju wahala ounjẹ to n fojoojumọ wọn-Akpabio

Adewale Adeoye

Aipẹ yii ni Olori ileegbimọ aṣofin agba ilẹ wa niluu Abuja, Senetọ Godswil Akpabio, sọ pe ijọba apapọ ilẹ wa ti fun awọn gomina ipinlẹ kọọkan lorileede yii ni biliọnu ọgbọn Naira lati fi yanju oke iṣoro tawọn araalu wọn n koju lori ọrọ ounjẹ to n fojoojumọ gbowo lori.

Akpabio sọrọ ọhun di mimọ lasiko to n ba awọn aṣofin ẹlẹgbẹ rẹ sọrọ nileegbimọ aṣofin agba niluu Abuja, pe owo ti ijọba apapọ ilẹ wa fun awọn gomina ọhun yatọ si owo ti wọn maa n gba lọwọ ijọba apapọ loṣooṣu tẹlẹ. O ni akanse owo nijọba apapo pe e, lati fi ran awọn eeyan ilu lọwọ lori ọrọ ounjẹ to n gbowo lori nigba gbogbo yii.

O waa rọ gbogbo awọn gomina ipinlẹ kọọkan pe ki wọn lo owo ọhun lọna ti yoo gba din iya ati iṣẹ ku laarin ilu wọn.

ALAROYE gbọ pe nipasẹ ajọ to n ri sọrọ owo-ori lorileede yii, ‘Federal Inland Revenue Service’ (FIRS) nijọba apapọ gba pin owo naa fawọn gomina ipinlẹ kọọkan.

Akpabio ni, ‘Ojoojumọ lawọn ọbayejẹ kan n ṣe onigbọwọ eto iwọde ita gbangba kaakiri orileede yii, wọn n ṣe eyi lati fi ba ijọba loju jẹ ni.Ṣugbọn awọn eeyan orileede yii ti wọn n lo ko mọ ipa ribiribi tawọn alaṣẹ ijọba n sa laarin ara wọn lati ri i pe awọn araalu ri ounjẹ jẹ. Lara rẹ ni ti owo gọbọi tijọba apapọ ṣẹṣẹ gbe fawọn gomina ipinlẹ kọọkan lorileede yii pe ki wọn fi yanju ọrọ ounjẹ to n fojoojumọ gbowo lori laarin ilu bayii.

Biliọnu ọgbọn Naira lowo ọhun. Eyi ki i ṣe lara owo ti wọn maa n gba lọwọ ijọba apapọ loṣooṣu tẹlẹ o, akanṣe owo nijọba apapọ pe e, ki wọn le fi tan gbogbo iṣoro airi ounjẹ to n ṣẹlẹ laarin ilu bayii ni.

‘Igbagbọ  ijọba apapọ ni pe awọn gomina ipinlẹ naa aa lo owo yii lati fi yanju ọrọ ounjẹ to n gbowo lori nigba gbogbo laarin ilu’.

Leave a Reply