O ṣẹlẹ! Awọn ọlopaa n wa eegun to kan baba agbalagba lẹ́ṣẹ̀ẹ́ pa

Adewale Adeoye

Ijọba ipinlẹ Anambra ti kede pe awọn n wa egungun adaṣọ-fun-jo kan to gbajumo daadaa laarin ilu Umuawulu, nijọba ibilẹ Akwa South, nipinlẹ Anambra. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o fẹṣẹ gbẹmi baba agbalagba kan, Oloogbe Shedrack Okoye, ẹni ọdun mọkanlelaaadọrin.

ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ ọhun waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2023.  Lasiko ti oloogbe ọhun n sin ọrẹ rẹ kan lọ sile ni egungun ọhun ti ọjọ ori rẹ ko ju ọdun mọkandinlogun lọ to n gbe lagbegbe Unuenu Umuawulu, beere owo ọdun lọwọ oloogbe ọhun. Nigba ti iyẹn taku pe oun ko lowo lọwọ lo ba bẹrẹ si i ku u lẹṣẹẹ, titi ti ẹmi fi bọ lara rẹ.

Kọmiṣanna fun ọrọ aṣa ati iṣe nipinlẹ naa, Ọnarebu Don Onyenji, ti bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ ọhun, paapaa ju lọ bi ara-ọrun naa ṣe ṣamulo ofin lọwọ ara rẹ nita gbangba.

Kọmiṣanna ọhun ni, ‘‘Ofin ipinlẹ naa ko faaye gba pe ki awọn egungun maa di awọn araalu lọna, tabi ki wọn fẹẹ gbowo lọwọ wọn pẹlu ipa. Ki wọn da awọn araalu laraya lasiko ayẹyẹ ọdun ni wọn wa fun, ki i ṣe lati maa fi halẹ mọ wọn tabi bakan.

Kọmiṣanna ọhun ni ẹsun ipaniyan ati iwa ọdaran lawọn maa fi kan egungun ọhun tọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ naa ba tẹ ẹ. Nitori pe ṣe lo ṣamulo ofin lati ọwọ ara rẹ.

O waa ba awọn ẹbi oloogbe ọhun kẹdun iku eeyan wọn to ku. Bakan naa lo rọ wọn pe ki awọn naa ma ṣe ṣamulo ofin lati ọwọ ara wọn lori iṣẹlẹ ọhun. O ni  ki wọn ṣe suuru, kijọba gbeja wọn ja.

O fi kun un pe awọn alaṣẹ ilu ibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye maa too ṣeranlọwọ gidi fawọn ẹbi oloogbe ọhun lati ṣeto isinku eeyan wọn ti eegun naa pa.

 

Leave a Reply