Ẹfun ree abeedi: Oyediran gun iyawo atọmọ-ọmọ ẹ pa l’Ọṣun

Florence Babaṣọla

Kayeefi lọrọ naa jẹ fun gbogbo awọn eeyan ilu Iniṣa, nijọba ibilẹ Odo-Ọtin, nipinlẹ Ọṣun, nidaaji ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, nigba ti awọn ọlọpaa n gbe oku iyawo ọkunrin nọọsi kan jade ninu ile rẹ pẹlu awọn ọmọ meji, ti wọn si ni baba won lo pa wọn.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ni nnkan bii aago mọkanla alẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja ni ede-aiyede bẹ silẹ laarin Oyediran atiyawo rẹ ti wọn jo jẹ alagba ninu ijọ Sẹlẹ, wahala naa pọ debii pe o pinnu pe ṣe loun yoo pa iyawo oun.

Oyediran ati iyawo ẹ to gun pa

O kọkọ ko awọn ọmọ mejeeji pamọ sinu ile-igbọnsẹ ko too di pe o gun iyawo rẹ lọbẹ pa, lẹyin igba yẹn lo lọọ gun awọn ọmọ mejeeji nikun ninu ile-igbọnsẹ, ti ifun wọn si tu jade. Lẹyin naa ni Oyediran rọra fi ọbẹ ge ara rẹ lapa ati nikun, o si lọ sileewosan kan niluu naa fun itọju.

Awọn agbenipa lawọn eeyan kọkọ lero pe wọn ṣiṣẹ ibi naa, ṣugbọn ninu iwadii awọn ọlọpaa ni wọn ti fura si Oyediran pe oun gan-an leku ẹda to da gbogbo rẹ silẹ. Ni wọn ba gbe e, o si ti wa lOṣogbo to n sọ ohun to ṣẹlẹ gan-an.

 

 

Leave a Reply